Mò ń mú inú àwọn ènìyàn dùn lọ́sàn án, mò ń w’ẹkún mu lóru – Abiola Adebayo
Mary Fágbohùn
Gbajumọ oṣerebinrin, Abiola Adebayo, ti kede pe igbeyawo oun ti tuka.
Ninu ọrọ kan to fi lede lori Instagram rẹ ni ọjọ Iṣẹgun, arẹwa oṣere naa kede pe lati oṣu kẹrin ọdun 2024, ni awọn ti pinya.
Oṣu kẹrin, ọdun 2021 ni Biola ati ọkọ rẹ atijọ, Oluwaseyi Akinrinde, ṣe igbeyawo wọn, ti wọn si bi ọmọ kan ṣoṣo to wa laarin wọn ni ọdun 2023.
“O wu mi ki igbeyawo mi tọjọ, sugbọn o san ki n wa laye lati fi ẹnu ara mi sọ iriri mi.”
Abiola Adebayo so pe, bi oun ṣe n mu inu awọn eeyan dun lọsan, ni oun n fi omije wẹ sun ni alẹ lati nnkan bii oṣu mẹrinla sẹyin.
O ṣalaye pe awọn mejeeji fẹnuko lati fọwọsowọpọ fun itọju ọmọ awọn.
Abiola Adebayo jẹ gbajugbaja oṣere tiata, to ti kopa ninu opolopo fiimu.
Ni ọjọ keje, oṣu kẹrin, ọdun 2021 ni o kede igbeyawo rẹ pẹlu ọkọ rẹ, Oluseyi, to si fi da awọn ololufẹ rẹ loju pe oun yoo mojuto ile oun, ti ko si ni faaye gba kudiẹkudiẹ kankan.