Ọdún kẹ̀ta rèé tí a ti ní iná ọba gbẹ̀yìn ní Ariwa Yewa, tírélà Dangote ló ba òpó iná wa jẹ́”
Fẹ́mi Akínṣọlá ẹ́ẹ̀ ọ́ọ̀ ńǹ
Àwọn èèyàn ìlú Ìbèsè , Ipokia, Imasayi àtàwọn ìlú mìíran ní ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Yewa ní ìpínlè Ògùn, ti rawọ ẹbẹ si ìjọba láti báwọn ṣe àtúnṣe iná ọba tó bà jẹ́ láwọn ìlú náà.
Wọn ni o ti pe ọdun mẹta ti ina mọnamọna ti tan nibẹ gbẹyin.
Lara awọn olugbe ilu naa, to ba akọroyin sọrọ ṣalaye pe, tirela Dangote lo ba opo ina awọn jẹ, eyi to si sọ awọn si okunkun birimu lati igba naa.
Aboro ti ilẹ Ibese, Ọba Rotimi Mulero, sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba pe otitọ ni pe awọn tirela ileeṣẹ Dangote ti wọn n ko simẹnti niluu naa lo wo awọn opo ina kan eyi to ba ina ọba jẹ.
Aboro ti ilẹ Ibese ni ”A kan si ileeṣẹ Dangote lori ọrọ naa wi pe awọn ni wọn ba ina ọba ilu wa jẹ, wọn so ina ọhun pada lasiko naa.
Amọ, ko ju ọjọ kan lọ ti ina naa tun fi bajẹ, ileeṣẹ Dangote tun gbiyanju lẹẹkeji lati tun ina naa ṣe, ṣugbọn ko tun kẹsẹ jari.
Ṣugbọn ti a ba fẹ sọ oootọ ọrọ, ileeṣẹ simẹnti Dangote to wa ni Ibese ti gbiyanju agbara wọn lori ọrọ ina yii,” Oba Mulero lo sọ bẹẹ.
Aboro ti ilẹ Ibese ni awọn lọbalọba ti kepe ileeṣẹ Dangote lori ọrọ ina ọba to bajẹ, ileeṣẹ naa si ti gbiyanju agbara wọn.
Ṣugbọn Ọba Mulero ni ọwọ ileeṣẹ mọnamọna ni ọrọ naa ku si bayii.
Jagunmolu Igbogila, Abdul Jelil Anisere, sọ pe o to ilu bi ogun labẹ ijọba Ariwa Yewa ti ko ni ina ọba bayii.
Olu ti Imasayi, Ọba Lukman Kuoye, ni ẹrọ amunawa lawọn n lo niluu naa latari airi ina lo.
Ọba Kuoye ni ”mo maa n ba ileeṣẹ simẹnti Dangote to wa niluu Ibese ṣe ajọṣepọ tẹlẹ lori ọrọ iṣoro naa, nigba ti wọn o ṣe nkankan lori rẹ ni mo ti fi wọn silẹ.
A ri wi pe lara awọn ọba wa naa n dakun iṣoro ina ọba yii tori ti a ba fẹnu ko lori nkan bayii, awọn naa ni wọn tun maa lọ gbẹyin bẹbọ jẹ.”
Ẹwe, adari ẹka ileeṣẹ apinaka IBEDC nipinlẹ Ogun, Abdul Rasaq Jimoh, ti ṣalaye fun BBC Yoruba pe awọn ti tun ina ọhun ṣe ni igba mẹta ọtọtọ ti awọn eeyan kan n ba a jẹ.
Ọgbẹni Jimoh ni ”awọn eeyan buruku yii ko da iṣẹ ibi wọn duro, niṣe ni wọn n tẹsiwaju lati maa ba gbogbo waya ti a ba tun ṣe jẹ.
A ti bawọn araalu papaa julọ awọn ọdọ ṣe ipade pọ wi pe ka jọ fọwọ sowọ pọ lati le daabo ina ọba ti a n tun un ṣe ni gbogbo igba, amọ, pabo ni gbogbo rẹ jasi.”
Ṣugbọn, Ọba Mulero sọ pe iwa aibikita ileeṣẹ IBEDC lo n fa a tawọn eeyan kan fi n ba waya wọn jẹ.
O ni ileeṣẹ naa lo yẹ ko wa awọn ti yoo maa ṣọ waya tabi nkan ti wọn lo fun atunṣe ina kii ṣe awọn awọn araalu.