Àgbà wá búra: Ebenezer Obey tú kẹ̀ẹ̀kẹ̀ ọ̀rọ̀ ṣílẹ̀ lórí itú méje tó pa nígbà èwe

Obey

Akeem Lasisi

– Obey ni obinrin kan ti oun ati Orlando jo n fe dija sile laarin won

– Obey ni oun maa n gbe awo orin meta jade laarin odun kan

– O ni oun ko fun omo egbe oun kankan laye lati gun oun gaagaa

– Baba Miliki s’alaye bi Ayinde Barrister se maa n sa to oun bi ile ba looyi

– Obey ni ota Wasiu Ayinde po

Ogunna gbongbo ninu awon akorin Naijiria ati kaakiri agbaye, Oloye Ebenezer Obey, ti siso loju eegun lori awon isele pataki kan to se nigba ti o wa ni sango ode.

Akorin pataki naa ti a tun mo si Baba Miliki se alaye ibasepo re pelu awon akegbe re, awon ti ko to o ninu ise orin, awon elegbe leyin re ati bi igbagbo ninu ebun ti Olorun fun un pelu ife si omolakeji se je e logun.

Bi apeere, Obey soro ohun to fa aawo tabi kontadiigbon laarin oun ati oloogbe Orlando Owoh nigba kan.

Gebe bi o ti wi, obinrin ko jo karuwa, ko jo nabi kan lo da ija naa sile.

Awon mejeeji jo n fe obinrin naa ni.

Orlando Owoh

Ohun to le pani lerin ni pe ile igbafe ale, iyen nightclub, ni obinrin naa maa n je si, ibe ni Obey si ti ri i.

Ibe ni won ti di ololufe.

Igbeyin-gbeyin ni Obey mo pe Orlando, iyen Baba Kennery, naa n na oja ti oun n na.

Obey ni lati igba ti Orlando ti mo lo ti n ba oun sote, to si maa n so fun oun pe awon ko le je ore.

Baba Commander tun fi kun un pe leyin opo odun ti isele naa ti sele, nigba ti ara Orlando ko ya, ti oun si wa lo si ile re ni adugbo Iyana Ipaja ni Ipinle Eko, Orlando ko je ki oun wole, ti oun si ni lati pada si soosi oun ti oun ti wa.

Inu fidio iforowanilenuwo kan ti Obey se pelu agbohunsafefe Agbaletu RadioVision ni o ti se alaye oro naa.

Ninu iforowanilenuwo yii, Obey so pe lawon asiko kan ti nnkan bureke, oun maa n gbe to awo orin marun-un jade laarin odun kan.

O tun soro lori awon omo egbe re kan ti won so pe o se awon.

Obey ni oun ko se aidara fun omo egbe oun kankan.

O ni ohun kan ti oun ko gba laye ni pe ki won ri oun fin tabi ki won te oun mere.

O ni owe oga meji ko le gbe inu moto kan ni oun fi lo igba ni t’oun.

Obey ni ti akorin kan ba gba awon omo egbe re laye lati je gaba le e lori, oju re yoo ri nnkan.

O se alaye ohun ti awon omo egbe Benjamin Adekunle foju re (iyen Adekunle) ri lasiko kan, ti won ni ko ma ta jita mo, ti won si fe so o di edun arinle.

Bakan naa, Obey seranti ajosepo oun ati oloogbe Sikiru Ayinde Barrister.

O ni loooto ni oun gba a nimoran pe ko mu ise orin kiko laayo nigba to si wa ni ise ologun.

Obey ni eniyan daadaa gba a ni Barrister, to si maa n bowo fun oun debi wi pe ‘Daddy’, iyen ‘Baba’, lo maa n pe oun.

Barrister

O wa fi kun un pe lawon asiko kan, oun maa n gba Barrister sile ninu laasigbo ise.

Obey ni Barrister le ti gba owo lowo awon onirekoodu kan lati gbe orin jade fun won sugbon ti ise awon ise naa ko ni tete jade.

O ni bi oro ba ti wa fe di ijongbon, odo oun ni Barrister maa n sa wa, ti oun yoo si petu si awon onirekoodu naa ninu.

Lori oro Wasiu Ayinde K1 de Ultimate, Obey ni eeyan daadaa ni oun naa.

O ni oun ti awuyewuye fi saaba maa n sele lakata Wasiu ni pe awon ota re po.

Obey ni Wasiu fi eyi jo oun tori awon ota oun naa po nigba kan.