Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe fẹ́ràn ìjọba Burkina Faso

Ìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn káàkiri àgbáyé ṣe fẹ́ràn ìjọba ológun Burkina Faso

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ẹni ọdún mẹ́tadínlógójì ni Ibrahim Traoré tó ń tukọ̀ Burkina Faso, ló ti ṣèlérí láti gba orílè-èdè náà silẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìjọba amúnisìn àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun.

Ọpọ eeyan ni Afrika lo fẹran ohun ti ọkunrin naa duro fun ti wọn si n woye pe o n tọ ipasẹ awọn adari rere to ti ṣejọba ṣaaju ni orilẹede naa bii Thomas Sankara.

Oluwadii kan ninu ajọ Control Risks sọ fun akọroyin pe “Ọpọ eeyan lo gba tirẹ. Mo ti gbọ ti awọn onkọwe atawọn oluṣelu lawọn orilẹede bii Kenya n sọ pe iru ọkunrin naas gan lawọn eeyan n wa.

“Awọn ọrọ to n sọ n ṣapejuwe bi aye ode oni ṣe ri ti pupọ awọn ọmọ ilẹ Afrika si n bere nipa ibaṣepọ ilẹ wọn pẹlu awọn oyinbo alawọ funfun ati eredi ti iya si fi n jẹ ọpọ eeyan ni Afrika lẹyin ti wọn gba ominira tan.

Lẹyin to fi ipa gba ijọba lọdun 2022, Traoré fopin si ibaṣepọ orilẹede rẹ pẹlu orilẹede France, to si tọwọ bọwe ajọṣepọ tuntun pẹlu Russia.

Lara awọn ohun to ṣe ni bo ṣe ṣagbekalẹ ileeṣẹ iwakusa ijọba, to si sọ pe awọn ileeṣẹ iwakusa ilẹ okeere gbọdọ maa san ida 15% owo ti wọn ba n pa fun ijọba ilẹ naa, ki wọn si maa gba awọn ọmọ orilẹ naa siṣẹ.

Lara awọn ti ofin naa kan ni ileeṣẹ Nordgold to jẹ ti orilẹede Russia.

Traoré sọ pe Burkina Faso gbọdọ jẹ lara ọrọ to wa ninu rẹ dipo ki awọn eeyan kan lati ilẹ okere maa ji ko.

Ijọba ologun rẹ tun kọ ileeṣẹ nla kan ti wọn ti n fọ wura, o tun ṣagbekalẹ ile nla ti wọn yoo maa ko wura iyebiye si, eyii to jẹ akọkọ iru rẹ lorilẹede ọhun.

Eyii n tumọ si pe awọn ileeṣẹ ilẹ okeere yoo maa koju isọro nibẹ.

Laipẹ yii ni ijọba Traoré gba ileeṣẹ iwakusa aladani lati ilẹ okere meji, so ti sọ pe oun ṣi maa ja ọpọ ileeṣẹ iwakusa lati ilẹ okere mii gba mọ awọn to n ṣakoso rẹ lọwọ.
Ọkunrin naa ti di gbajumọ lori ayelujra ti awọn eeyan si n kọ oniruru nnkan nipa rẹ, yala o jẹ ododo abi bẹẹ kọ.

Koda, awọn eeyan ti lo ẹrọ AI lati ṣe fidio bi awọn gbajumọ bii R Kelly, Rihanna, Justin Bieber ati Beyoncé ṣe n kan sara si lọna ati jẹ ki awọn eeyan tunbọ gba tirẹ.

Asiko ti ọkunrin naa sọrọ nibi ipade Afrika ati Russia kan lọdun 2023 ni irawọ rẹ kọkọ buyọ lasiko to sọ fun awọn adari ni Afrika ki wọn dẹkun ati maa sa tọ awọn alawọ funfun lọ fun iranlọwọ ni gbogbo igba.

Awọn ileeṣẹ iroyin ni Russia gbe iroyin naa to bẹẹ to fi tan kaakiri agbaye.

Amọ ṣa, lara awọn ti ko gba ti Traoré ni Aarẹ France, Emmanuel Macron.

Bo tilẹ jẹ pe o kuna lati pari ijijagbara awọn ẹlẹsin Musulumi kan to ti n waye fun ọdun mẹwaa gẹgẹ bi ileri rẹ, awọn eeyan ṣi gba tirẹ.

Ijọba ni o tun fiya jẹ awọn ti ko gba tirẹ atawọn ọmọ ẹgbẹ alatako.

A gbọ pe ijọba Traoré tun gbogun ti awọn akọroyin to n kọ iroyin ti ko tẹ lọrun, bẹẹ lo n fi oju awọn ẹgbẹ ajafẹtọọmọniyan ri mabo.

Nigba ti igabkeji adari ajọ International Crisis Group, Rinaldo Depagne, n da si ọrọ naa, o ni awọn eeyan fẹran Traoré ni Afrika latari pe o jẹ ọdọmọde.

O ni “O mọ nipa ori ayelujra daadaa – o si mọ bi wọn ṣe n fun orilẹede ti ogun ti sọ dahoro ni igbagbọ pe wọn ni ọjọ ọla rere.”

Depagne sọ fun akọroyin pe “O ni imọ nipa oṣelu daada o si mọ bi wọn ẹ n wu eeyan lori.”

Ọdun 1983 ni Sankara gori alefa lẹyin iditẹgbajọba kan nigba to wa lẹni ọdun mẹtalelọgbọn ki wọn to gbẹmi oun naa lẹyin ọdun mẹrin ninu iditẹgbajọba mii.

Lẹyin iditẹgbajọba naa ni orilẹede wọn ti wa labẹ ojiji orilẹede France ki Traoré to gba ọpa aṣẹ ilẹ naa bayii.

Onimọ nipa eto abo orilẹede ghana, Ọjọgbọn Kwesi Aning sọ fun akọroyin pe “Ijọba awarawa ti kuna lati fun awọn ọdọ ni ireti ọjọ ọla to dara ni Afrika, ko fun awọn ọdọ naa niṣẹ tabi eto ilera to peye.”

Gẹgẹ bo ṣe sọ, Traoré n fun awọn ọdọ naa ni ọna abayọ lo mu ki wọn fẹran rẹ.
Traoré lawọn eeyan sọ oju si lara julọ lasiko iburawọle Aarẹ Ghana, John Mahama.

Niṣe lo wọ gbagede eto naa pẹlu aṣọ ologun lọrun rẹ toun ti ibọn ilewọ lẹgbẹ rẹ.

Ọjọgbọn Aning ni “Olori orilẹede mọkanlelogun lo ti wa nibẹ ko to de ṣugbọn nigba ti Traoré wọle, ariwo sọ, koda awọm ẹṣọ alabo Aarẹ mi gan n sare tete tẹle lẹyin.”

Traoré yatọ si awọn Aarẹ ni Afrika to n fi agidi di ipo ijọba mu.

Ninu atẹjade kan ti ajọ IMF fi lede ninu oṣu Kẹrin ọdun yii, IMF sọ pe bo tilẹ jẹ pe nnkan le ti eto abo si mẹhẹ, eto ọrọ aje orilẹede naa yoo gberu si lọdun yii.
Wayi o, oniruru iroyin lo ti n gbode pe awọn kan n gbe igbesẹ lati fi agidi yọ ọdọkunrin naa lori oye.

Olufẹhonuhan kan to tun jẹ olorin, Ocibi Johann sọ fun ileeṣẹ iroyin Associated Press pe “Nitori Collin Powel pa irọ, wọn sọ Iraq dahoro. Brack Obama parọ, wọn gbẹmi Gaddafi. Ṣugbọn lasiko yii, irọ wọn ko ni tu irun kankan lara wa.”

Yatọ si orilẹede naa, awọn eeyan ṣe iwọde kaakiri agbaye, pẹlu ilu London nilẹ Gẹẹsi, ni atilẹyin fun Traoré.

Lẹyin awọn iwọde naa lo dupọ lọwọ awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye fun atilẹyin wọn.

Yoo ṣoro lati sọ bi igbẹyin rẹ yoo ṣe ri amọ oun atawọn ologun ni Mali ati Niger ti da rugudu silẹ ni Afrika, awọn orilẹede mii si ti n le awọn ọmọ ogun France kuro nilẹ wọn gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe ṣaaju.

Yatọ si eyii, awọn orilẹede mẹta naa tun ti fa ara wọn yọ kuro ninu ẹgbẹ ajọ Ecowas.

Amọ awọn onimọ ti sọ pe Traoré gbọdọ ṣiṣẹ ki alaafia jọba to ba fẹ ni akọsilẹ rere dipo ko maa gbogun ti awọn ti ko ba fẹran rẹ.