Ọlọ́pàá ń lo àyẹ̀wò DNA fún àwọn ọmọ tí wọ́n rí he nírònà
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn ọlọpaa ní East London ti bẹrẹ sí ní ya ojúlé sí ojúlé báyìí láti ṣàwarí ìyá ọmọ kékeré jòjòló kan tí wọ́n rí lẹ́ẹ̀bá ọ̀nà.
Ileeṣẹ ọlọpaa naa ni awọn ti ya ojule to le ni irinwo bayii ninu igbiyanju awọn lati ṣawari iya ọmọ naa.
Inu apo kan ni wọn ti sawari ọmọ ọhun ti wọn pe orukọ rẹ ni Elsa lagbegbe Newham ki ẹnikan to n mu aja rẹ rin to ri.
Nigba ti wọ n ṣayẹwo ẹjẹ DNA rẹ, wọn ṣawari pe ọmọ naa n ibatan meji mii – ọkunrin ati obinrin – ti wọn ti kọkọ ṣawari lẹba ọna bii tirẹ lọdun 2017 ati 2019.
Bo tilẹ jẹ pe ọlọpaa ti n rawọ ẹbẹ pe ki awọn obi ọmọ naa jade, wọn ko tii mọ ẹyẹ to ṣu awọn ọmọ mẹta naa titi di asiko yii.
Lati ọsẹ marun un sẹyin lawọn agbofinro ilẹ Gẹẹsi ti jawe sobi akitiyan wọn lati ṣawari awọn obi awọn omọ naa, wọn si fun akọroyin lanfani lati maa tẹle wọn kiri bi wọn ṣe n ṣiṣẹ ọhun.
Ọlọpaa ti bẹrẹ si ni kan ilẹkun ile awọn eeyan lagbegbe naa bayii lati maa gba DNA wọn lati ṣayẹwo rẹ boya o ba ti ọmọ tuntun naa mu.
Wọn tun ti n kan si awọn ti wọn fi DNA wọn silẹ lọdọ ijọba lati wo o boya o ba ti awọn ọmọ ọhun mu.
Lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2017 ni wọn kọkọ ri Harry ni nnkan bii maili kan sibi ti wọn ti ṣawari Elsa yii.
Inu igbo kan ni ọmọ naa wa pẹlu aṣọ ti wọn fi we lara.
Ọdun kan ati oṣu mẹrin lẹyin naa ni wọn ri ibatan rẹ obinrin, Roman, lori ijoko gbọrọ kan ni gbagede ti awọn ọmọde ti n ṣere.
Ọlọpaa ni inu apo ti wọn fi n ta ounjẹ nile itaja igbalode ni wọn gbe ọmọ naa si ninu aṣọ kan lasiko otutu.
Awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to ṣawari awọn ọmọ ọhun lo fun wọn lorukọ ti wọn n jẹ.
Ayẹwo DNA fi han gbangba pe iya kan naa lo bi awọn mejeji.
Ọdun marun un lẹyin awọn mejeji ni wọn ri Elsa ti ayẹwo wọn si fi han pe iya kan naa lo bi awọn mẹtẹta.
Ninu oṣu Kinni ọdun 2025 yii ni ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba kede pe oun yoo san £20,000 fun ẹnikẹni to ba le ṣamọna bi ijọba yoo ṣe ri iya tabi awọn obi ọmọ naa.