Ìdí tí Tinubu ṣe fi òfin de kíkó àwọn ọjà kan wọlé sí Nàíjíríà

Ìdí tí Tinubu ṣe fi òfin de kíkó àwọn ọjà kan wọlé sí Nàíjíríà

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Bola Tinubu ti fòfin de kíkó ọjà wọlé láti ilẹ òkèèrè sí Nàìjíríà pàápàá jùlọ àwọn nǹkan tí orílè-èdè Nàìjíríà lè ṣe.

Aarẹ Tinubu tun sọ gbedeke iye awọn akọṣẹmọṣẹ ilẹ okeere to le wọ Naijiria lati wa ṣiṣẹ tawọn ọmọ Naijiria naa le ṣe funra wọn.

Minisita eto iroyin ati ilanilọyẹ, Mohammed Idris, lo fidi ọrọ yii mulẹ lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ to waye nileeṣẹ ijọba l’Abuja lọjọ Aje eyi ti Aarẹ Tinubu dari rẹ.
Minisita ni igbesẹ nla ti yoo mu idagbasoke ba ọrọ aje Naijiria ni igbesẹ ti aarẹ gbe yii, ati pe yoo tun mu igbelarugẹ ba awọn nnkan ti orilẹede Naijiria n pese.

Ọgbẹni Idris ni ọkan gboogi ni igbesẹ yii jẹ ninu akitiyan ijọba aarẹ Tinubu lati mu ọrọ aje Naijiria pada bọ sipo.
O ni Tinubu n wo awokọṣe Aarẹ Donald Trump Amẹrika pẹlu bi Trump ṣe kede wi pe orilẹede Amẹrika ni akọkọ ninu gbogbo nnkan ti ijọba oun n ṣe lọwọ yii.

Minisita eto iroyin sọ pe igbesẹ yii ko ni jẹ ki orilẹede Naijiria gbẹkẹle ọja ilẹ okeere nikan mọ

”Eto yii yoo jẹ ki aṣa okowo tuntun eyi to ni ṣe pẹlu orilẹede Naijiria nikan gbilẹ daadaa.

Igbesẹ yii yoo tun jẹ kawọn ọmọ Naijiria jẹ anfaani okowo ijọba pẹlu bi ijọba ṣe n nawo, ra ọja ati bi wọn ṣe n mu eto ọrọ aje gbooro,” Minisita lo sọ bẹẹ.

Minisita eto iroyin ati ilanilọye sọ pe aarẹ ti sọ fun agbẹjọro agba ni Naijiria lati sọ igbesẹ naa di ofin.

O ni igbesẹ yii ti yoo maa ṣe igbelarugẹ nnkan ti orilẹede Naijiria n pese jẹ ọkan gboogi ninu eto imugbooro ọrọ aje ijọba Aarẹ Tinubu.

Ọgbẹni Idris sọ pe ajọ Bureau of Public Procurement (BPP) gbọdọ ri pe gbogbo ẹka ijọba lo n lo nnkan ti wọn ṣe ni Naijiria bayii.

Minisita ni ajọ BPP yoo ṣe akojọpọ awọn olokowo ọmọ Naijiria ti wọn yoo maa ta nnkan ti wọn n ṣe fun gbogbo ileeṣẹ ijọba.

Ọgbẹni Idris fikun ọrọ rẹ pe ajọ BPP ti fi awọn oṣiṣẹ wọn si gbogbo ileeṣẹ ijọba lati maa tọpinpin bi wọn ṣe n lo nnkan tawọn ileeṣẹ ati olokowo Naijiria n ṣe.

O ni lati akoko yii lọ ko si ileeṣẹ ijọba to gbọdọ ra nnkan ti wọn n ṣe ni Naijiria nilẹ okeere mọ.

Minisita ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ti o ba pọn dandan ki ijọba tabi ẹnikẹni lo agbaṣẹṣe lati ilẹ okeere, iru agbaṣẹṣe bẹẹ gbọdọ lo imọ ẹrọ ni Naijiria tabi ko kọ awọn ọmọ Naijiria ni iru imọ ẹrọ to ba n gbe bọ wa Naijiria.

Idris ni gbogbo ileeṣẹ ijọba ni lati sọ erongba wọn lori nnkan ti wọn ba fẹ ra fun ijọba bayii.

O ni ijiya wa fun ileeṣẹ ijọba to ba kọ lati ṣe bẹẹ, ati pe ijọba yoo fagile nnkan ti wọn fẹ ra nilẹ okeere.

Minisita ni ileesẹ ti wọn ti n ṣe ṣuga wa lara awọn ileeṣẹ to nilo itaji ni Naijiria.

Idris ni nnkan ti ko bojumu ni bi Naijiria ti n ko ṣuga wọle lati ilẹ okeere nigba ti ileeṣẹ to n ṣe ṣuga ni Naijiria ti dẹnukọlẹ.

O ni awọn agbaṣẹṣe ko ni lanfaani lati maa ko ọja to ba wu wọn wọle si Naijiria mọ, nigba tawọn ileeṣẹ Naijiria n ku lọ.

Minisita ni owo ijọba gbọdọ maa ṣiṣẹ fawọn ọmọ Naijiria bayii.