Ọ̀gá Àgbà àjọ JAMB banújẹ́ , lórí èsì ìdánwò UTME ọdún 2025 tó jáde

Ọ̀gá Àgbà àjọ JAMB banújẹ́ , lórí èsì ìdánwò UTME ọdún 2025 tó jáde

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ JAMB tó ń ṣàkóso ìdánwò àti gbaniwọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì àt’àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga mìíràn ní Nàìjíríà ti sọ pé àṣìṣe wà ninú èsì ìdánwò UTME tọdún 2025 yìí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde.

Ọgagba àjọ JAMB, Ọjọgbọn Ishaq Oloyede, bú sẹ̀kun gbaragada nígbà tó fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ fáwọn akọ̀ròyìn lónìí Ọjọ́rú nílùú Àbújá.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Oloyede ní “nǹkan tó yẹ kó jẹ́ ayọ̀ ti di ìbànújẹ́ nítorí àṣìṣe tó wáyé.”
Akòwé àgbà JAMB náà kéde pé bíi 379,997 àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe ìdánwò naa ni yóò tún ìdánwò ọhun ṣe báyìí.

Eyi ko ṣẹyin awọn kudiẹ kudiẹ to waye to ṣokunfa bi ọpọ akẹkọọ ṣe fidirẹmi ninu idanwo naa.
Ajọ JAMB fidi rẹ mulẹ loju opo X rẹ pe mẹtadinlọgọjọ (157) ninu aadọrun-un le lẹẹgbẹrin din mẹta (887) ibi ti idanwọ ọhun ti waye ni aṣiṣe ti waye.

Ajọ naa sọ pe eyi gan lo ṣokunfa bi maaki ọpọ akẹkọọ ti ṣe idanwo lawọn ibikan ṣe lọọlẹ gan an.

NI bayii, gbogbo awọn akẹkọọ tọrọ kan ni ajọ JAMB yoo kan si lati tun idanwo naa ṣe laipẹ.

Lọjọ Aje to kọja ọjọ kejila oṣu Karun un yii ni ajọ JAMB kede pe awọn yoo ṣe agbeyẹwo esi idanwo UTME ọdún 2025 t’awọn gbe sita.
Agbẹnusọ ajọ JAMB, Fabian Benjamin, ṣalaye pe igbimọ alaṣẹ ajọ naa yoo ṣe agbeyẹwo ọhun ni kiakia.

O ni gbogbo ohun to ni ṣe pẹlu idanwo naa ni wọn yoo ṣe agbeyẹwo rẹ fínífíni.

Eyi ṣẹlẹ tori bi ọpọ eeyan ṣe sọrọ nipa esi idanwo UTME ọdún yìí eyi ti ọpọ akẹ́kọ̀ọ́ fìdírẹmi ninu rẹ.

Ọgbẹni Benjamin sọ saaju wipe ajọ JAMB yoo ṣe ohun to tọ tó bá jẹ pe loootọ ni kudiẹ kudiẹ wa ninu eto idanwo naa.
Ṣaaju ni ọpọ ọmọ Naijiria, paapaa julọ awọn ti esi idanwo naa kan gbọngbọn, ti bọ sori ayelujara lati fi ẹdun ọkan wọn han.

Ọpọ akẹkọọ lo ni esi idanwo tawọn gba kọja gan-an ko buru to ti 2025 yii.

Akọle kan ti i ṣe #thisisnotmyresult, ni awọn eeyan naa n lo lati fi aidunnu wọn han, ti wọn si n pe fun atunyẹwo esi idanwo yii.

Esi ti JAMB fi sita kede pe bii miliọnu kan aabọ akẹkọọ (1.5 million candidates), ni ko gba to maaki igba (200) ninu idanwo naa.

Itumọ eyi ni pe ida ọgọrin (80%) akẹkọọ ni ko gba maaki igba ninu irinwo (400).

Iṣẹ mẹrin ti maaki ọkọọkan jẹ ọgọrun-un (100) ni awọn akẹkọọ naa jokoo ṣe ninu UTME, apapọ rẹ lo jẹ irinwo (400).

JAMB ṣalaye pe akẹkọọ yoo kọkọ fi orukọ silẹ, yoo jokoo ṣedanwo, esi yoo si jade. Igbesẹ mẹta naa ko ju bẹẹ lọ.