Àjọ NAPTIP k’ọ́mọ Naijiria 78 padà wálé lóko ẹrú Abidjan
Fẹ́mi Akínṣọlá
Kò dín ní ọmọ orilẹede Naijiria méjì dínlọ́gọ́rin (78), ti àjọ tó n gbógun ti fífini sọ̀kọ̀ sílẹ̀ ibòmí-ìn; National Agency for the Prohibition of Trafficking in Persons (NAPTIP), kó padà sí orílẹ-èdè yìí báyìí láti Abidjan, orílè-èdè Côte d’Ivoire.
Nnkan bii aago mọkanla ku iṣeju mẹẹẹdogun alẹ ọjọ Satide ni baaluu to gbe wọn balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed, l’Ekoo.
Binta Adamu Bello, ọga agba NAPTIP to tẹwọ gba awọn eeyan naa, ṣeleri pe awọn to wa nidii iwa ifinisọko silẹ okeere lọna aitọ naa yoo koju ofin.
”Ṣaaju ni a ti kọkọ mu awọn eeyan kan to wa nidii okoowo to lodi sofin yii, wọn yoo si foju bale-ẹjọ.
”Si ẹyin ti ẹ pada wale yii, a ba yin yọ, a si fẹẹ kẹ ẹ mọ pe orilẹede Naijiria wa pẹlu yin”
Bẹẹ ni ọga NAPTIP wi.
Bakan naa ni ajọ yii ti bẹrẹ ajọsọ pẹlu awọn alẹnulọrọ l’Abidjan, eyi to n ṣe akọsilẹ awọn ọmọ Naijiria to foju wina ilokulo naa.
Gẹgẹ bi ọga NAPTIP ṣe wi nipa awọn ṣẹṣẹ de ọhun, o ni o to awọn mẹrin ninu awọn ọmọbinrin aarin wọn ti wọn wa ninu oyun.
Ọjọ ori awọn ọmọ naa ko to nnkan kan, gẹgẹ bi alaye NAPTIP.
Wọn fi kun un pe ọjọ ori awọn eeyan naa wa laaarin ọdun mẹtala si ọgbọn ọdun.
Bakan naa ni NAPTIP fidi ẹ mulẹ, pe awọn ọmọ ọwọ tun wa lara awọn ṣẹṣẹ de lati Abidjan naa.
Lapapọ, obinrin marundinlọgọrin (75) lo wa ninu ni awọn ti wọn ko de naa, ọmọ ọwọ meji.
Wọn fi kun un pe awọn ọkunrin meji kan naa tun wa ti wọn mu kuro loko ẹru ilokulo ti wọn ba ara wọn l’Abidjan.
Irisi awọn eeyan naa fi han pe ọhun o rọgbọ rara, ebi ati iṣẹ han lara wọn.
Ọkan lara wọn, Clara( ki i ṣe orukọ rẹ gan-an) ṣalaye pe oun le ma bọ ninu idaamu toun pa pade l’Abijan.
O ni awọn ọga fi gbogbo iya jẹ awọn patapata, ko si jọ pe oun le gbagbe gbogbo ohun oju ri lẹyin odi.