Baálẹ̀ Yẹmí Ògúnyẹmí,àgbà ọ̀jẹ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, jáde láyé

Baálẹ̀ Yẹmí Ògúnyẹmí,àgbà ọ̀jẹ̀ agbóhùnsáfẹ́fẹ́, jáde láyé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gbajúgbajà agbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ó tún jẹ́ Baálẹ̀ agbègbè Oluyọle nílẹ̀ Ìbàdàn, Olóyè Yẹmí Ògúnyẹmí, ti jáde láyé.

Ọjọ Iṣẹgun, tii ṣe ọjọ kẹfa oṣu Karun ni olokiki agbohunsafẹfẹ naa re iwalẹ aṣa lẹyin ailera oṣu meloo kan.

Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe, DSP Wale Ogunyẹmi ṣe alaye fun akọroyin pe lati bii oṣu meloo kan sẹyin ni Oloye Ogunyẹmi ti n ṣe aisan.

O ni gbogbo ipa si ni awọn sa lati doola ẹmi baba awọn nipa gbigbe wọn lọ si ile iwosan.

Wale Ogunyemi ni amọ aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se, ninu igbiyanju wọn lati doola ẹmi rẹ si ni ọlọjọ ti de ba a nile iwosan UCH to n bẹ nilẹ Ibadan.
DSP Ogunyẹmi ni, “Abiyamọ tootọ to nifẹ ọmọ ni baba wa.

O si ko gbogbo ẹbi ati araalu mọra, eeyan takuntakun ati eeyan daadaa ni baba wa.

Ki Ọlọrun fi ori jin wọn, a o ṣe afẹri wọn lọpọlọpọ”

Lati igba ti iroyin ipapoda Baalẹ Yemi Ogunyemi naa ti lu sita ni ọkanojọkan ariwisi ti n waye lori itakun ayelujara.

Ọpọ awọn ololufẹ wọn si lo n fi aworan wọn lede, ti wọn si n kọ oriṣiriṣi ọrọ ibanikẹdun.

Lara wọn ni Ademọla Babalọla ti o jẹ alaga ẹgbẹ akọroyin, NUJ ipinlẹ Ọyọ.
Ni gbogbo ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun ni Oloye Ogunyẹmi maa n ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi.

Saaju ọrọ oye jijẹ, iṣẹ igbohunsafẹfẹ ati atọkun eto gan an ni Oloye Ogunyẹmi yan laayo.

Ọkan gboogi lara awọn eto to sọ Oloogbe naa di olokiki lẹnu iṣẹ igbohunsafẹfẹ ni eto kan ti wọn pe ni ‘Ẹ Ń BÁ LÁYÀ’ nile iṣẹ tẹlifisan NTA ilẹ Ibadan ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Bakan naa ni Oloye Ogunyẹmi tun jẹ atọkun eto kan ti wọn pe ‘AGBỌRANDUN’ nibi ti wọn ti n yanju oriṣiriṣi aawọ.

Yatọ si eto ṣiṣẹ lori afẹfẹ, Alagba Ogunyẹmi fi igba kan jẹ alakoso NTA ilu Ọyọ nigba aye wọn.

Awọn si ni igbakeji aarẹ awọn Baalẹ ilẹ Ibadan titi ti ọlọjọ fi de.