Oọ̀ni ṣe pàtàkì fún ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú Naijiria – Goodluck Jonathan

Oọ̀ni ṣe pàtàkì fún ìṣọ̀kan àti ìlọsíwájú Naijiria – Goodluck Jonathan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ààrẹ Nàìjíríà nígbà kan rí ri, Goodluck Ebele Jonathan, ti júwe Ooni Ilé Ifẹ́, Oba Adeyeye Ogunwusi, àti Sultan ìlú Sokoto, Alhaji Sa’ad Abubakar, gẹ́gẹ́ bíi àwọn orí adé méjì tó ṣe pàtàkì fún ìsọ̀kan Nàìjíríà.

Jonathan lo sọ ọrọ naa ni ilu bibi rẹ, Otuoke, to wa nipinlẹ Bayelsa.

Agbẹnusọ Ooni, Moses Olafare sọ ninu atẹjade kan pe Jonathan ni gbogbo igba ni ijọba apapọ maa n kan si awọn ori meji naa ti nnkan ba fẹ yiwọ latari ipo ti wọn di mu lawujọ.
Jonathan sọ pe “Ẹbun nla ni Ooni jẹ fun ilẹ Afrika.

“Ni gbogbo igba ti ijọba apapọ ba fẹ kan si awọn lọbalọba ni Naijiria, awọn meji pataki to maa n ke si ni Ooni ati Sultan. Awọn mejeji jẹ ori ade to ṣe pataki ni Naijiria.

“Nigba ti mo wa nipo Aarẹ Naijiria, igbimọ awọn lọbalọba fi Sultan ati Ooni jẹ alaga – nibi ti Sultan ti n ṣoju iha Ariwa, ti Ooni si n ṣoju Guusu, eyii n sọ bi ipo Ooni ṣe tobi to ni Naijiria.

Aarẹ Naijiria tẹlẹ naa tun sọ bo nifẹ ipinlẹ Osun to, o si ṣalaye pe ilu Iresi, nipinlẹ Osun loun ti sinlu gẹgẹ bii agunbanirọ.

Lasiko abẹwo rẹ si Bayelsa, Ooni tun ṣe ipade pẹlu gomina ipinlẹ naa, Douye Diri atawọn igbimọ rẹ, to fi mọ igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ ọhun.
Nigba to n sọrọ nibi ipade naa, Ooni Ogunwusi ṣalaye pe irẹpọ laarin awọn ọmọ Naijiria ṣe pataki fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.

Ooni sọ pe “A ko ni orilẹede mii yatọ si Naijiria. Fun Naijiria lati tẹsiwaju, a gbọdọ gba alaafia laaye, alaafia ko si le waye lai si ifọwọsowọpọ. Ibi ti awọn lọbalọba ti gbọdọ fọwọ ti ijọba lẹyin ree.”

Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ki wọn gbaruku ti Aarẹ Bola Tinubu ninu afojusun rẹ lati tun Naijiria ṣe.

Nigba to n sọrọ, gomina Diri sọ pe apẹrẹ isọkan ati orukọ rere ni Ooni jẹ.

Diri ni bo tilẹ jẹ pe eeyan nla ni Ooni, iwa irẹlẹ rẹ jẹ eyii to n wu awọn eeyan lori.

Lẹyin naa lo ni awọn lọbalọba ipinlẹ naa bu iyi nla fun Ooni.