O̩wó̩ padà te̩ Iliyasu tó sè̩mí màmá 65 légbodò l’Ékòó
Yínká Àlàbí
Yoruba bo̩, wo̩n ni “bi aja pe ogun o̩dun laye, e̩ran ogun ni”. O̩wo̩ awo̩n agbofinro pada te̩ afunrasi Abubarkar Iliyasu ti wo̩n f’e̩sun kan pe o pa mama e̩ni o̩dun marundinlaado̩rin ni adugbo Orile Iganmu.
Ge̩ge̩ bi alukoro awo̩n o̩lo̩paa ni ipinle̩ Eko, O̩gbe̩ni Benjamin Hundeyin se salaye. Ipinle̩ Kogi ni o̩wo̩ awo̩n agbofinro ti te̩e̩, wo̩n si tun gba o̩ko̩ ayo̩ke̩ke̩ Toyota Sienna to ji pe̩lu awo̩n e̩ru mama naa.
Ko̩miso̩na o̩lo̩paa ni ipinle̩ Eko, o̩gbe̩ni Olohunde Jimoh fi gbogbo ara ilu lo̩kan bale̩ pe ki awo̩n ara ilu Eko lo̩ fo̩kan bale̩. Oni nipa o̩ro̩ awo̩n onijibi, o̩mo̩ to ni baba oun ko ni sun, oun naa ko ni foju b’orun ni awo̩n maa fi o̩ro̩ awo̩n alo̩-kolohun kigbe naa se.
O ni nipa Iliyasu ti o̩wo̩ te̩ ati awo̩n ake̩gbe̩ re̩ ti awo̩n ti ko̩ko̩ mu lo maa f’oju ba ile e̩jo̩ ti awo̩n ba ti pari iwadii.