Wike to̩ro̩ àforíjì ló̩wó̩ Olure̩mi Tinubu
Yínká Àlàbí
Ajo̩ oluranlo̩wo̩ to n se ironi-lagbara ti aya Aare̩ Orileede yii Se̩neto̩ Olure̩mi Tinubu n dari (Renewed Hope Initiative Empowerment programme) ni wo̩n digba dagbo̩n lo̩ si ilu Port Harcourt ti se olu-ilu ipinle̩ Rivers.
Dide ti wo̩n debe̩ ni awo̩n obinrin ti wo̩n titori wo̩n lo̩ sibe̩ dide ti wo̩n si yan ko̩ja lai bikita iyawo Aare̩.
Iroyin jade pe wo̩n se eyi lati fi ehonu wo̩n han si iyawo Aare̩ pe inu awo̩n ko dun bi ijo̩ba apapo̩ se yo̩ Siminalayi Fubara ti o je̩ gomina te̩le̩ ni ipinle̩ naa.
Eyi lo mu ki minisita fun olu-ilu Naijiria, Nyesom Wike jade lati be̩be̩. Ge̩ge̩ bi o̩gbe̩ni Lere O̩layinka tii se olubani-damo̩ran pataki lori o̩ro̩ ayelujara se salaye. O ni awo̩n to s’afojudi naa ko s’oju ipinle̩ Rivers. O ni awo̩n o̩lo̩te̩ lasan ni wo̩n.
Ajo̩ ironi-lagbara naa ko gbogbo awo̩n e̩ru bii – freezers, gas cookers ati ovens, generators ati masinni ilo̩ta lorisiirisii naa pada.
Eniyan e̩e̩de̩gbe̩ta ni wo̩n ni lo̩kan lati ro lagbara ni ana o̩jo̩ ke̩ta, osu ti a wa yii.