ẸKÚN ÌYÀWÓ
Òkóńkòkó ni mí o
Tí mo kósùpá r’Òṣogbo
Tí mo w’ẹ̀wù oyè r’Ọbaàgùn
Orí tí ó d’olóyè kìí fẹ́
Orí mi ó d’olóyè bó dọ̀la
Ire lónìí, orí mi àfi’re
Mọ̀mọ́ mi, mọ̀mọ́ mi
Mọ̀mọ́, mo ní n wá gba’re tèmí
Kí n tó máa lọ
Ire tèmi ò mọ̀mọ̀ pọ̀
Ire mi ò mà kún wọ́
Ire ẹja lómi ló kúkú mọ
Ire kọ̀ǹkọ̀ lódò ló mà wà
Ire ọmọ bíbí inú ìyá o
Ìlúmọ̀mí bí ò tó mi lẹ́rù n ò lọ o
Ire lónìí, orí mi àfi’re
Bùlenge, bùlenge
Bùgé bùgé àkàrà
Mo ní ò ṣe lẹ́yìn erèé
Bùlenge ọmọ ń bẹ lọ́wọ́ yeye
Mọ̀mọ́ tí mo mú s’àkọ́bí o
Mọ̀mọ́ mi fún mi ní bùgé-bùgé ṣe
Ire lónìí, orí mi àfi’re.
- Lati inu iwe EKUN IYAWO lati owo Akeem Lasisi
- Contact: 08023687884