Wọ́n ti kó ọmọ Nàìjíríà 203 tó há sí Libya padà wálé

Wọ́n ti kó ọmọ Nàìjíríà 203 tó há sí Libya padà wálé

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó ń dáhùn sí ìṣẹlẹ pàjáwìrì lórílẹ̀ -èdè yìí ti sọ pé ọmọ Nàìjíríà tí iye wọn jẹ́ igba-lé-mẹ́ta (203) làwọn ti gbà wọlé báyìí láti orílè-èdè Libya tí wọ́n há sí tẹ́lẹ̀.

Ajọ International Organization for Migration (IOM) pẹlu ajọṣepọ ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, ‘National Emergency Management Agency’ (NEMA), ni wọn ko wọn wale pẹlu awọn alẹnulọrọ mi-in.

Oju opo X ajọ NEMA ni wọn ti kede eyi lọjọ Iṣẹgun.

Nnkan bii aago mẹje alẹ ọjọ Isegun naa ni NEMA kede pe wọn balẹ si papakọ ofurufu Murtala Muhammed, Ikeja.

Ọkọ ofurufu Al Buraq ti nọmba rẹ jẹ 5A-BAC ni wọn lo ko wọn de.

Wọn ṣalaye pe awọm ọmọ Naijiria naa ko ri ọna ti wọn yoo gba fi Ariwa Libya ti wọn ti le wọn kuro silẹ ṣaaju asiko yii, ko too di pe iranlọwọ de fun wọn.

Kete ti wọn balẹ si papakọ ofufurfu Murtala Muhammed, ni awọn alaṣẹ ti tẹwọ gba wọn.

Agbalagba ọkunrin ti wọn jẹ aadọta niye (50), agbalagba obinrin mẹrindinlọgọrun (96), ọmọde mọkandinlọgbọn (29) ati awọn ọmọ ọwọ mejidinlọgbọn (28) ni awọn eeyan naa.

Atẹjade ti NEMA fi sita ṣalaye pe meji lara awọn ọkunrin naa ni wọn nilo itọju pajawiri nigba ti wọn ko wọn de.

Ileewosan ijọba to wa n’Ikeja ni wọn sare gbe wọn lọ fun itọju bi NEMA ṣe sọ.