Àwọn alága káńsù tuntun àti làásìgbò ní ìpínlẹ̀ Rivers

Àwọn alága káńsù tuntun àti làásìgbò ní ìpínlẹ̀ Rivers

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ọ̀rọ̀ burúkú ṣòde kánrin.
Àwọn jàǹdùkú kan ti dáná sun àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ kan nì ìpínlẹ̀ Rivers tí wọ́n sì ti lé gbogbo àwọn Alága káńsù tí wọ́n ṣẹṣẹ dibo yan sípò dà sígbó lọjọ Ajé.

Eyi waye lẹyin ti wọn ko awọn ọlọpaa kuro lawọn sẹkitariati ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Rivers.

Iroyin ti a gbọ n sọ peawọn janduku naa ti sọ ina si awọn sẹkitariati ijọba ibilẹ Ikwerre, Eleme, Obio/Akpor ati Emohua nigba ti iroyin si tun n sọ pe awọn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn jẹ awọn ọmọlẹyin minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesom Wike ti gba akoso awọn ijọba ibilẹ Ahoada West, ti ẹmi kan si tun ti lọ ni ijọba ibilẹ Ahoada East.

Lawọn ijọba ibilẹ yoku, awọn alaga tuntun ti bẹrẹ iṣẹ wọn ni irọwọrọsẹ ti wọn si ti ṣeto ibura fun awọn kansilọ igbimọ aṣofin ijọba ibilẹ wọn ki awọn ikọlu naa to waye.

Gomina Siminalayi Fubara ti bura fun awọn alaga ijọba ibilẹ mẹtẹtalelogun ti wọn dibo yan lẹyin ti wọn fun wọn ni iwe ẹri idiboyansipo wọn lẹyin eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta.

Awọn ọlọpaa ko tii sọ ohunkohun lori awọn wahala to n ṣẹlẹ yii amọṣa awọn alaṣẹ ọlọpaa ti paṣẹ pe ki gbogbo ọlọpaa kuro lawọn sẹkiteriati to wa ni ipinlẹ Rivers.

Nigba ti ọrọ oṣelu ni ipinlẹ naa di oruyeye loṣu kẹfa ọdun 2024 ni wn ko awọn ọlọpaa da sawọn sẹkiteriati ijọba ibilẹ.

Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Rivers, SPGrace Iringe-Koko sọ ninu atẹjade kan pe ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria lo paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọlọpaa naa kuro.

SP Irin-Koko sọ pe “igbesẹ naa waye ni ibamu pẹlu ipinnu ileeṣẹ ọlọpaa lati duro lai ṣegbe ati iduro deede awọn ilana ijọba tiwantiwa.” O ni idi ti awọn ọlọpaa fi wa lawọn ijọba ibilẹ wọnyii tẹlẹtẹlẹ naa ni lati dena wahala.

Ẹgbẹ oṣelu Actions Peoples Party, APP lo bori gẹgẹ bi alaga ni ijọba ibilẹ mejilelogun ninu mẹta lelgun to wa ni ipinlẹ Rivers ninu ibo ijọba ibilẹ to waye lopin ọsẹ to kọja, gẹgẹbi alamojuto agba fun eto idibo ti ajọ eleto idibo ipinlẹ Rivers gbe kalẹ, Adajọfẹyinti Adolphus Enebeli ṣe sọ lasiko to kede esi idibo ni ilu PortHacourt lọjọ Satide.

Igba akọkọ niyi ti ẹgbẹ oṣelu alatako yoobori eto idibo ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Rivers lati ọdun 1999, nitori pe ṣaaju asiko yii ẹgbẹ oṣelu to ba wa nipo gẹgẹ bi gomina lo maa n ko gbogbo mudumudun ibo naa.

Oludije fun ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, Uzodinma Nwafor lo bori esi idibo alaga ibilẹ ni ijọba ibilẹ Etche.

Orukọ awọn alaga tuntun ti gomina ipinlẹ Rivers, Seminalayi Fubara ṣebura fun ni:

Vincent Obu – ijọba ibilẹ Abua/Odual,
Chibudom Ezu – ijọba ibilẹ Ahoada-East,
Iyekor Ikporo – ijọba ibilẹ Ahoada-West,
Tonye Oniyide – ijọba ibilẹ Akuku-Toru,
Lazarus Nteogwuile – ijọba ibilẹ Andoni,
Sule Amachree – ijọba ibilẹ Asari-Toru,
Anengi Barasua – ijọba ibilẹ Bonny,
Harry Agiriye – ijọba ibilẹ Degema
Brain Gokpa – ijọba ibilẹ Eleme.
David Omereji – ijọba ibilẹ Emohua,
Monday Dumiye – ijọba ibilẹ Gokana,
Isreal Abosi – ijọba ibilẹ Ikwerre,
Martins Nwigbo – ijọba ibilẹ Khana,
Chijioke Ihunwo – ijọba ibilẹ Obio/Akpor,
Ọmọọba Isaac Umejuru – ijọba ibilẹ Ogba-Egbema-Ndoni,
Ishmael Oforibika – ijọba ibilẹ Ogu/Bolo,
Ọmọọba Igwe Achese – ijọba ibilẹ Okrika
Promise Reginald – ijọba ibilẹ Omuma.
Enyiada Cookey-Gam – ijọba ibilẹ Opobo/Nkoro,
Gift Okere – ijọba ibilẹ Oyigbo,
Ezebunwo Ichemati – ijọba ibilẹ Port Harcourt
Matthew Nenubari Dike – ijọba ibilẹ Tai.
Atiku atawọn gomina lẹgbẹ oṣelu PDP kan sara si Fubara fun iwa akin rẹ

Ẹgbẹ oṣelu PDP to n dari ijọba ni ipinlẹ Rivers ko kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to waye ni ipinlẹ naa, amọṣa o awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP naa kan ti kan sara si gomina Fubara pe o fi ọkan akin ṣe eto ijọba ibilẹ naa pẹlupẹlu gbogbo wahala ọrọ oṣelu to n ṣẹlẹ nibẹ.

Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar sọ pe abajade ibo naa fihan pe awọn eeyan ipinlẹ naa ti kọ ipakọ si iwa oṣelu baba isalẹ, oniwahala ati onijagidijagan.

Gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed, to tun jẹ alaga igbimọ awọn gomina lẹgbẹ oṣelu PDP kan sara si i.

Awọn gomina ipinlẹ lẹgbẹ oṣelu PDP sọ pe apẹrẹ rere leyi jẹ fun ẹgbẹ oṣelu naa.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here