Ìdí tí àwọn Ọlọṣun ṣe ń gbé ìkókó o wọn wọnú odò lẹ́yìn ìbímọ

Ìdí tí àwọn Ọlọṣun ṣe ń gbé ìkókó o wọn wọnú odò lẹ́yìn ìbímọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìdálùú nìṣèlú,
Ọ̀jìnmì onímọ̀ nípa ẹ̀sìn ìbílẹ̀ pàápàá jùlọ ìmọ nípa ifá Olóyè Ifáyẹmí Elẹ́buìbọn tó jẹ́ Àràbà ti ìlú Òsogbo tó mọ̀ nípa àṣà àti ohun tó rọ̀ mọ́ ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àlàyé pé gbogbo ẹ̀bí ní ilẹ̀ Yorùbá ló ní àṣà àti ìṣe mọ̀lẹ́bí wọn tó jẹmọ́ ẹ̀sin kóówá wọn ní èyí tí wọn ń fi lé ọmọ lọ́wọ́.

Elẹ́buìbọn sọ pe gbigbe ọmọ wọnu odo jẹ ọkan lara aṣa awọn idile Olosun to jẹ wi pe oriṣa Ọṣun ni wọn n bọ. O sọ pe eyi jẹ ọna kan lati fi Osun mọ ọmọ naa gẹgẹ bi oriṣa ajọbọ ti idile wọn.

Odo ni agbegbe Ilaje
Ati pe: “Gbigbe ikoko wọnu odo jẹ ọna lati mu oju ọmọ naa mọ iṣẹṣe ati aṣa idile Olọsun”

Elẹ́buìbọn tun sọ pe igbesẹ naa ko mu ewu dani rara fun ikoko naa nitori pe obinrin agbalagba to ni iriri lo maa n gbe awọn ikoko naa wọnu odo ti ko jin pupọ.

O tun sọ pe igbesẹ naa jẹ ọkan lara iṣẹṣe to n fi oju ọmọ naa mọ pataki omi ati igbagbọ idile rẹ ninu oriṣa Osun ni eyi to saaba maa n waye lasiko ti ikoko naa ba wa laarin ọmọ oṣu meji si mẹfa.

Lakootan,yatọ si pe igbesẹ gbigbe ikoko wọnu odo jẹ ọkan lara ọna iṣẹṣe lati ṣe afihan ikoko si aṣa Yoruba; O tun jẹ ọna ti awọn kan gbagbọ pe wọn fi n da ọmọ ọkọ mọ yatọ si ọmọ ale eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Deoxyribonucleic acid testing (DNA).

Ko tii si imọ ijinlẹ sayẹnsi kankan to ti fi idi awọn nnkan wọnyi mulẹ ati pe awọn iran kọọkan ti n pa wọn rẹ nitori ọlaju ati ẹsin miran.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here