Ètò o̩rò̩ ajé tí kò de̩rùn: Àkókò tó dára láti gbé orin ‘e no easy’ (kò ro̩rùn) jáde nìyí – Erigga so̩ fún P-Square
Mary Fágbohùn
Leyin bi nnkan ti se le koko bi oju eja kaakiri orile ede, gbajumo olorin Naijiria, Erhiga Agarivbie ti a mo lori itage si Erigga ti fi ateranse sowo si awon akegbe re, P-Square.
Erigga ninu atejade kan to fi lede lori X, so fun P-Square pe asiko to dara lati gbe orin won ilumooka ni ‘E No Easy’ jade re e.
Nigba to n fesi si ifehonu han to n lo lowo, o ko o pe: “Asiko yi lo ye ki P-Square ko orin “ e no easy eh.”
Irohin jade pe oro ti Erigga so yi waye laarin ifehonu han kaakiri orile ede ti o n lo lowo ti won fi ori re so #Efiopinsietoisejobatikodara eyi to gbera so lati ojo kinni osu kejo si ojo kewa osu kejo odun 2024.
E ranti pe awon olorin yi gbe orin “E no Easy” ni odun 2009.