Ẹnikẹ́ni kò le dáwa l’ọ́wọ́ kọ́ láti málo gbàgede Eagles Square l’Abuja fún ìfẹ̀hónúhàn – Alákòso ìwọ́de.

Ẹnikẹ́ni kò le dáwa l’ọ́wọ́ kọ́ láti málo gbàgede Eagles Square l’Abuja fún ìfẹ̀hónúhàn – Alákòso ìwọ́de.

Gbọ́láhàn Quseem

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn alakóso fún ètò ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn ‘ebi n pa wá,’ èyí tí ọmọ Nàìjíríà n gbèrò nínú oṣù Kẹjọ, ọdún yìí ti sọ pé ẹnikẹ́ni kò lè d’áwọn lọ́wọ́kọ́ láti málo gbàgede Eagle Square tó wà nílùú Abuja.

Ọgbẹni Damilare Adenola to je alakoso eto fun ẹgbẹ Take It Back Movement sọ eyi lọjọ Aiku to kọja nibi ifọrọwerọ to ṣe nile-iṣẹ kan.

Adenola sọ pe awọn ko ni adari tabi baba isalẹ kankan to n sagbatẹru ifẹhonuhan to fẹẹ waye, bi ko ṣe pe gbogbo ọdọ Naijiria ti ebi n pa ni wọn pawọpọ lati jade sita sọ ẹdun ọkan wọn.

Lati bi ọsẹ meloo sẹyin ni ariwo naa ti n lọ ni kikan-kikan ni’gboro pe awọn ọdọ fẹ korajọ lati ṣe iwọde ifẹhonuhan ilẹ Naijiria, nibi ti wọn ti n beere fun ayipada ninu eto ati ilana iṣejọba.

Ifẹhonuhan ọhun l’awọn eeyan ti n pariwo lori ikanni ayelujara kaakiri agbaye, ati pe gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria lawọn ọdọ ati ara-ilu yo ti pejọ f’ẹhonuhan ọhun.

Ki ṣe ahesọ wi pe owo ounjẹ ati gbogbo nkan ti lọ soke, leyi to ṣoro fun ara-ilu lati mu ọwọ lọ sẹnu, iyẹn lati ‘gba ti ijọba ti kede yiyọ owo iranwọ ori epo ti a mọ si ‘subsidy’.

Adenola sọ pe dukia ijọba to wa fun lilo ara-ilu ni gbagede Eagle Square jẹ, to si ni Minisita fun ọrọ eto FCT, Nyesom Wike ko ni nkan meji to fẹ ṣe ju lati gba wọn laaye lọ.

Lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun ti a wa yi ni awọn ọdọ buwọ lu lẹta kan ti wọn fi ranṣẹ si Minisita Nyesom Wike, nibi ti wọn ti n beere fun anfaani lati lo gbagede Eagle Square fun eto ifẹhonuhan wọn.

Ṣugbọn ṣa, Minisita fun FCT, lọjọ Abamẹta to kọja sọ pe oun ko ti gba lẹta lati ọdọ ẹnikẹni tabi ẹgbẹ kankan wi pe awọn fẹ lo Eagle Square.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here