NAFDAC gbẹsẹ lé ayédèrú oògùn amárale táwọn ọkùnrin fi ń ṣe ‘kerewà’ ní Sókótó

NAFDAC gbẹsẹ lé ayédèrú oògùn amárale táwọn ọkùnrin fi ń ṣe ‘kerewà’ ní Sókótó

Fẹ́mi Akínṣọlá

Àjọ tó rí sí oúnjẹ jíjẹ àti òògùn lílò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ‘National Agency For Food And Drug Administration And Control’ (NAFDAC), ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Sókótó, ti kéde pé àwọn ti gbẹ́sẹ̀ lé òbítíbitì ayédèrú òògùn òyìnbó kan táwọn ọkùnrin máa ń lò tó máa ń fún wọn lágbára láti bá obìnrin sùn dáadáa tí wọ́n kó wọ̀lú náà lọ́nà àìtọ́

Ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun yii, ni Ọga agba patapata fun ajọ naa nipinlẹ Sokoto, Ọgbẹni Garba Adamu, sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nipa aṣeyọri wọn nipinlẹ Ṣokoto ati agbegbe rẹ lọdun yii.

O ni, ‘A ti gba obitibiti ayederu oogun oyinbo kan tawọn ọkunrin maa n lo lati fi ba awọn obinrin sun, a ṣewadii daadaa nipa oogun ọhun, a si ni ẹri to daju ṣaka pe awọn eroja kan ti wọn fi ṣoogun ọhun ko daa fun lilo awọn araalu, akoba nla gbaa ni oogun naa maa fa fun awọn ti wọn ba lo o lọjọ iwaju.

O waa rọ awọn araalu ọhun, paapaa ju lọ awọn ọkunrin ti wọn maa n lo awọn oogun to le jẹ ki wọn ba obinrin sun daadaa lasiko ibalopọ pe ki wọn jawọ ninu iwa palapala naa, nitori pe ki i ṣe ohun to daa fara rara, to si ni ipalara fun wọn lọjọ iwaju.

O ni bi wọn ba maa ra oogun yoowu, ki wọn ri i daju pe eyi to jẹ ojulowo, to si ni ontẹ NAFDAC lara ni wọn ra lọja.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here