Ọba Ọlákùlẹ́yìn gbọ̀pá àṣẹ gẹ́gẹ́ bí Olúbàdàn Kẹtàlélógójì
Fẹ́mi Akínṣọlá
Wọ́n ní orì tí yóó dádé, inú agogo idẹ ní tií wá,ọrùn tí yóó lèjìgbà ìlẹ̀kẹ̀,inú agogo idẹ ní tií wá, ìbàdí tí yóó lo mọ́sàajì, aṣọ Ọba tí í taná yanranyanran,,inú agogo idẹ ní tií wá, èyí ló bí bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé ti gbé ọ̀pá àṣẹ fún Olúbàdàn tuntun,níbi àkànṣe ètò ìfinijoyè tó wáyé ní gbàgede Mapo nílùú Ìbàdàn l’ọ́jọ́ Ẹtì .
Nínú ọ̀rọ̀ tí Mákindé sọ níbi ìpéjọpọ̀ náà, ó ṣe àlàyé wí pé ìgbésẹ̀ tí òun gbé láti fún Olúbàdàn tuntun ní ọ̀pá àṣẹ àti ìwé ẹ̀rí ìyanisípò wà ní ìbámu pẹ̀lú agbára tí a fún un gẹ́gẹ́ bíi Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
Lẹ́yìn tí Olúbàdàn tuntun Ọba Owólabí Ọlakulẹhin, Ige Ọlakulẹhin 1 gba ọ̀pá àṣẹ ni Kábíyèsí náà dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó wá sí ibi àjọyọ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń gbàdúrà pé ìlú Ìbàdàn yóó máa gòkè àgbà síi.
Àwọn ládéládé-lóyèlóyè, aṣojú ìjọba, àwọn alákòóso ẹgbẹ́ òṣèlú, àwọn asíwájú ẹ̀ṣin àti ọ̀kanòjọ̀kan ẹgbẹ́ àwùjọ kò gbẹ́yìn níbi àkànṣe ètò náà.
Lára wọn ni Mínísítà fún àkóso iná ọba, Adebayo Adelabu tí ó ṣojú Ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí, Bọla Ahmed Tinubu, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Onímọ̀ Ẹ̀rọ Ṣèyí Mákindé, Igbákejì rẹ̀, Adebayo Lawal, Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn, Dapọ Abiọdun, igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Òǹdó, Olaide Adelami, igbákejì Gómìnà Ọ̀ṣun, Kola Adewusi, Ọọ̀ni Ilé Ifẹ̀, Ọba Adewusi Enitan Ogunwusi, Sultan Sokoto, Sa’ad Abubakar, Ewi Ado, Oba Rufus Adeyemo Adejugbe, Olugbon Orílé Ìgbọ́n, Ọba Francis Olusola Alao Asẹ́yìn ìlú Ìṣẹ́yìn, Sefiu Oyebola Adeyeri III, Ajirotutu I, Olú Igboọra, Ọba Jimoh Olajide Titiloye, Olóyè Rashidi Ladọja àti àwọn Gómìnà tẹ́lẹ̀rí n’ípìínlẹ̀ Ọyọ, Ààrẹ Mùsùlùmí ilẹ̀ Yorùbá, Edo àti Delta, Alhaji Dauda Akinola, Kọmisana Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọyọ, Ayọdele Ṣonubi, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Gbajúgbajà olórin, Taye Currency ló kan ìlù sí àwọn èèyàn n’íbàdí níbi ìpéjọpọ̀ náà.