Gómìnà Seyi Makinde buwọ́lu ìyànsípò Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olubadan

Gómìnà Seyi Makinde buwọ́lu ìyànsípò Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olubadan

Fẹ́mi Akínṣọlá

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti buwọ́lù iyansipo Oba Akinloye Owolabi Olakunleyin gẹ́gẹ́ bíi Olúbàdàn ti ilẹ̀ Ìbàdàn.

Olakunleyin ni yóò jẹ Olúbàdàn ẹkẹtalelogoji nínú ìtàn ilẹ̀ Ìbàdàn.

Gómìnà kéde ìgbésẹ̀ yìí nínú ọrọ̀ kan tó fi léde èyí tó ti buwọ́lu láti ọjọ́ kẹrinla oṣù kẹfà ọdún 2024, ní òun pàṣẹ pẹ̀lú ìlànà tí ìwé òfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti ọdún 2000 gbé kalẹ̀.

Nínú atẹjade ti Kọmisọna fún ọrọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ àti oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Olusegun Olayiwola fi léde fún àwọn akọroyin, ó ní ìgbésẹ̀ yìí wáyé ní ìlànà tí òfin ti ṣètò nípa oyè jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nínú atẹjade náà, Gómìnà Seyi Makinde kí Olúbàdàn tuntun náà kú oríire, tó sì gbà á ladura pé ìgbà rẹ̀ yóó san gbogbo aráàlú Ìbàdàn.
Bẹ́ẹ̀ bá gbàgbé, Ọba Owolabi Olakunleyin ti sọ pé tàbí ṣugbọn kan kò sí, òun ni ipò Olúbàdàn kan.

Lásìkò tí ikọ alabẹwo láti ọdọ Gómìnà Ṣèyí Makinde lọ kí bàbá náà nílé rẹ̀ lágbègbè Alalubọsa, n’Ibadan ló sọ bẹ́ẹ̀.

Alàgbà Ọlakulẹyin ní òun ti ṣetán láti gun ori ìtẹ, àti pé ọpẹ́ ló kàn lọrọ òun.

Alàgbà Ọlakulẹyin tó sọrọ pẹlú ohun tó já geere, sí iyalẹnu ọpọ èèyàn tó wà níbè, sọ pé, “ Inú mi dùn láti rí àwọn ikọ alabẹwo láti ọdọ Gómìnà.

‘’ Nígbà tí wọ́n sọ fún mi pé ẹ ń bọ̀, ẹsẹkẹsẹ ni mo sọ fawọn olóyè mi pé kí wọ́n máa bọ̀, kí wọ́n jẹ́ ká jọ gbà yín lálejò.

‘’ Inú mi dùn pé àwọn èèyàn mìíràn wà níbí pẹ̀lú mi.

‘’Mo ti ṣetán pátápátá. Mo mọ pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn mi. Ó ti sọ pé èmi ni ipò Olúbàdàn kàn, èmi náà sì mọ òdodo pé èmi ló kan, àsìkò mi rè é .’’

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here