Ọpẹ́ o! Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹjọ táwọn agbébọn jí gbé ní Kwara gbàdáǹdè
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kwara, pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ẹgbẹ́ fijilanté àti àwọn ọmọ ológun ti dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga Fasiti Confluence Science and Technology, tìlúu Osara, ìpínlẹ̀ Kogi, táwọn agbébọn jí gbé ní bíi ọjọ́ mélòó kan ṣẹyin, tí wọ́n sì ti wà ní àkàtà ọlọ́pàá Kwara báyìí.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, DSP Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fi sita lọjọ Aiku, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, to tẹ akọròyìn lọwọ sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa, pẹlu ifọwọsowọpọ ẹgbẹ fijilante ati awọn ọmọ ologun, ti doola ẹmi awọn akẹkọọ mẹjọ kan ti awọn ajinigbe ji gbe nipinlẹ Kogi. Gẹgẹ bo ṣe wi, o ni ni kete ti olobo ta ileeṣẹ ọlọpaa ni Kwara, pe awọn agbebọn wa ninu igbo kan lagbegbe Òrò-Àgọ́, nipinlẹ naa, ni Kọmiṣanna ọlọpaa, CP Ọlaiya Victor, paṣẹ ṣe ki awọn ẹṣọ alaabo ya wọ inu igbo ọhun, ti wọn si doola ẹmi awọn akẹkọọ mẹjọ kuro lakata awọn ajinigbe naa, o ni mẹjọ ni wọn, obinrin marun-un ati ọkunrin mẹta.
Orukọ wọn ni, Anate Hanifa Oyiza, ẹni ọdun mọkandinlogun, Damisa Rashida Ometere, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Ahmed Tijani Fatimah, ẹni ọdun mọkanlelogun, Obakachi Mashkurah Onyioyiza, ẹni ọdun mẹtadinlogun, Ọlọruntọba Blessing Kẹmisọla, ẹni ọdun mẹtalelogun, Omojo Godwin, ẹni ọdun mọkandinlogun, AbdulRafiu Abdulmakik Enesi, ẹni ọdun mọkandinlogun ati Musa Oseni, ẹni ọdun mọkandinlogun, ti wọn si ko gbogbo wọn lọ si agọ ọlọpaa ẹka Òrò-Àgọ́. A gbọ pe wọn ṣi maa ko gbogbo wọn lọ siluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, fun ayẹwo ati itọju to peye nileewosan.
O tẹsiwaju pe awọn ẹṣọ alaabo ti n sa ipa wọn lati ṣawari awọn agbebọn ọhun, ti wọn aa si fimu kata ofin.
CP Ọlaiya, ti ni ki gbogbo olugbe Kwara lọọ fọkanbalẹ, aabo to peye wa pẹlu wọn, ti wọn ba si kẹfin iwa aitọ lagbegbe wọn, ki wọn fi to awọn agbofinro leti.
O lu ọga ọlọpaa patapata nilẹ yii, Kayọde Ẹgbẹtokun, lọgọ ẹnu pẹlu bi wọn ṣe n ṣiṣẹ takuntakun pẹlu awọn ẹṣọ alaabo yooku lati gbogun ti iwa ọdaran ati ijinigbe lorile-ede yii