Ìdájọ́ ikú ló yẹ kí wọ́n máa fún àwọn ajínigbé– Rẹmi Tinubu
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìlú tí kò sófin, àwọn àgbà ní ẹ̀ṣẹ̀ kò sí níbẹ̀.
Obìnrin àkọ́kọ́ l’órílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abilékọ Olurẹmi Tinubu, ní ẹjọ́ ikú ló yẹ kí wọ́n máa dá fún gbogbo àwọn ọ̀daràn tí wọ́n bá ti jẹ̀bi ẹ̀sùn tó bá ti ní í ṣe pẹ̀lú ìjínigbé.
Ìyàwó Ààrẹ sọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń fi ìmọ̀lára rẹ̀ hàn lórí bi àwọn agbébọn ṣe ya bo ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Kaduna láàárọ̀ Ọjọ́bọ, ọjọ́ keje, oṣù yìí, ti wọ́n sì jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tó bíi ọrinlelugba (280) pẹ̀lú àwọn olùkọ́ wọn kó lọ.
Rẹmi Tinubu ní ìgbàgbọ́ òun ni pé ẹnikẹni tó bá ti ń lọ́wọ́ nínú jíjí àwọn ọmọ kéékékèké gbé gbọdọ̀ jẹ́ aláàárẹ̀, ọ̀dájú àti ojo ènìyàn.Ó ní báwo lẹni tó gbádùn tàbí níláárí kan ṣe lè wò sùnsùn, kò sì lọ̀ọ́ ka àwọn ọmọ kéékékèké mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn láti jí wọn gbé lọ.
Gẹ́gẹ́ bíi ẹni tó ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l’Abuja, Ìyàwó Ààrẹ ní àsìkò ti tó fún àwọn aṣòfin Nàìjíríà kí wọ́n tètè ṣòfin tí yóó máa fi ìyà ńlá jẹ gbogbo ọdaràn tó bá ti jẹbi ẹsùn ìjínigbé, nítorí àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní: ‘má fi oko mi ṣ’ọna, ọjọ́ kan náà lèèyàn ń pinnu rẹ̀ ’.