Ilé-ẹjọ́ gba béèlì Ta-ni-Ọlọrun lẹ́yìn ọjọ́ márùndínlọ́gọ́rin láhàámọ́
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àtẹ̀bi àtàre, kí Ọlọ́run má jẹ́ á rógun ẹjọ́ ni ìwúre ọ̀pọ̀ ẹ̀dá ní
dúníyàn,ṣùgbọ́n àdúrà yìí kò fi gbogbo ara gbà fún ọkùnrin kan tí ó ti wà lákàtà ọgbà àtúnrọ fúngbà díẹ̀ sẹ́yìn kó tó di pé Ilé-ẹjọ́ Májísìrètì kan tó fìlú Ìlọrin ṣe ibùjókòó gba béèlì rẹ̀,Abdulazeez Adegbọla, tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ Ta-ni-Ọlọrun, lẹ́yìn ọjọ́ márùndínlọ́gọ́rin lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Ta-ni-Ọlọrun ló ti ń jẹ́jọ́ láwọn ilé-ẹjọ́ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, Upper Area ati Májísìrètì, nílùú Ilọrin, lórí ẹ̀sùn ìbanilórúkọjẹ́ tí ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní Association of Proud Sons and Daughters of Ilọrin (Ogo Ilọrin) àti Aafaa Okutagidi, fi kàn án.
Ọ̀kan lára àwọn agbẹjọro tó ń dúró fún un, Muftau Olobi, ló tún gbé ìwé béèlì lọ síwájú ilé-ẹjọ́ Májísìrètì lọjọ Ajé, ọgbọ̀njọ́, oṣù Kẹwàá yìí, pé kí adájọ́ wo oníbàárà rẹ̀ ṣe, kó fún un ní béèlì kó máa wáá jẹ́jọ́ láti ilé rẹ̀ nítorí pé oníbàárà òun ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn tó ṣẹ fún ìdáríjìn.
Agbẹjọ́rò tó ń sojú ogo Ilọrin, Oseni Sanni, kò ta ko ẹ̀bẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n ó gba ilé-ẹjọ́ níyànjú láti gbé àwọn ìlànà tí yóó mú olujẹjọ náà máa yọjú sí ilé-ẹjọ́ ní gbogbo ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ kalẹ̀.
Májísìrètì Muhammad Ibrahim, gbà sí àwọn méjèèjì lẹ́nu, ó fún olùjẹ́jọ́ náà ní béèlì ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba Náírà (N200, 000), àti onídùúró méjì, tí ọ̀kan nínú wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìbátan rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí Májísìrètì Muhammad Ibrahim ṣe là á kalẹ̀, áwọn onídùúró yìí gbọdọ̀ máa gbé ní agbègbè ilé-ẹjọ́, olujẹjọ náà sì gbọdọ̀ máa fara hàn ńIlé-ẹjọ́ ní ẹẹkan láàárín ọjọ́ mẹrinla.
Lẹ́yìn èyí ló sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá.
Tẹ ò bá gbàgbé, ilé-ẹjọ́ Upper Area ti gba béèlì Ta-ni-ọlọrun, láti bíi oṣù kan ṣẹ́yìn, ṣùgbọ́n tí Májísìrètìkọ láti gba béèlì rẹ̀, èyí tó mú un lo ọjọ́ pípẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Òkè-Kúrá, nílùú Ìlọrin. Ṣùgbọ́n ní báyìí, Májísìrètì náà ti gba onídùúró rẹ̀, tí yóó sì máa ti ilé lọ jẹ́jọ́.