Akọ̀ròyìn Al-Jazeera pàdánù ẹbí ẹ̀ sínú ìkọlù Israel sí Gaza

Akọ̀ròyìn Al-Jazeera pàdánù ẹbí ẹ̀ sínú ìkọlù Israel sí Gaza

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé wọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ogun là á rí, kò séèyàn tó lè sọ ye ẹ̀mí òhun dúkíà tí àjálù tógun fà yóó fọwọ́ kó lọ.
Ọ̀kan ni ti àwọn ẹbí akọ̀ròyìn ilé iṣẹ́ ìròyìn Al-Jazeera kan ti ó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìkọlù tó wáyé ní Gaza.

Ìkọlù ọ̀hún ló wáyé ní ààrin gbùngbùn Gaza lẹ́yìn tí Israel ṣèkìlọ̀ fún àwọn ènìyàn láti kúrò ní àríwá Gaza.

Ìyàwó Wael Al-Dahdouh, àtàwọn ọmọ rẹ̀ méjì pàdánù ẹ̀mí wọn ní ilé àwọn aṣatìpó tó wà ní ààrin gbùngbùn Gaza gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Al-Jazeera ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀.

Bákan náà ni ìròyìn tún ní ọmọ-ọmọ rẹ̀ tún bá ìkọlù ọ̀hún lọ.

Al Jazeera bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà àtàwọn ìkọlù tí Israel ń ṣe sí Gaza.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn Al-Jazeera, àwọn ẹbí Al-Dahdouh ń gbé ní ilé kan nínú ọgbà Nuseirat tó wà ní àárín gbùngbùn Gaza lẹ́yìn tí wọ́n kúrò ní ilé wọn ní àríwá Gaza látàrí ìkìlọ̀ tí Israel ṣe fún wọn láti kó lọ sí gúúsù nítorí ogun tó ń wáyé níbẹ̀.

Mahmoud, ọmọ Al-Dahdouh, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ti wà ní ìpele tó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ girama, tí Sham sì jẹ́ ọmọ ọdún méje.

Adam tó jẹ́ ọmọ-ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọmọ oṣù méjìdínlógún.

Àwọn ẹbí mìíràn ni wọ́n sin sábẹ́ àwọn ilé tó dàwó ṣùgbọ́n àwọn mìíràn móríbọ́ nínú ìkọlù náà.

Iléeṣẹ́ ètò ààbò Israel (IDF) ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ṣe ìkọlù sí ikọ̀ Hamas ní agbègbè ibi tí àwọn ẹbí Al-Dahdouh ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Àwòrán Al-Dahdouh tó wà lórí ayélujára ṣàfihàn bí ó ṣe ń dá omi lójú nílé ìwòsàn bí ó ṣe di òkú ọmọbìnrin, ọmọ ọdún méje rẹ̀ dání, tó sì kúnlẹ̀ ti ọmọkùnrin rẹ̀.

Al-Jazeera ní àwọn kọminú lórí ààbò àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó wà ní Gaza tí wọ́n sì fi ààbò wọn kọ́ ìjọba Israel lọ́rùn.

“A rọ àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé láti dá sí ọ̀rọ̀ yìí, kí wọ́n sì fi òpin sí ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ará ìlú, kí ààbò le wà fún ẹ̀mí àwọn ènìyàn.”

Gaza ló ti ń kojú ìkọlù látọwọ́ Israel lẹ́yìn tí ikọ̀ Hamas ṣe ìkọlù àìròtẹ́lẹ̀ sí Israel ní ọjọ́ Keje oṣù Kẹwàá níbi tí èèyàn tó lé ní 1,400 ti pàdánù ẹ̀mí wọn.

Ènìyàn tó lé ní igba tó jẹ́ ọmọ Israel ló ṣì wà ní àhámọ́ Gaza títí di àsìkò yìí.

Iléeṣẹ́ ètò ìlera tí ikọ̀ Hamas ń ṣe àmójútó rẹ̀ tó wà ní Gaza ní ó lé ní ẹgbẹ̀rún méje ènìyàn tí Israel ti ṣekúpa.

Israel ti ṣe ìdádúró pípèsè epo, iná àti omi sí agbègbè náà láti ìgbà tí ìkọlù náà tí bẹ̀rẹ̀.

Láti orílẹ̀ èdè Egypt ni ìwọ̀nba ìrànlọ́wọ́ ti ń wọlé sí Gaza.