Ìrọ̀lóyè Ghandi ti dá ògo àti orúkọ rere ìdílé wa padà – Ìdílé Laoye

  • Ìrọ̀lóyè Ghandi ti dá ògo àti orúkọ rere ìdílé wa padà – Ìdílé Laoye

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ṣé àwọn ní bí ohun gbogbo bá yí padà, bí n ó ṣe ṣe nǹkan mi nìyí kò yí padà torí ẹlẹ́nu rírùn ló làmù ìyá rẹ̀.
Ìdílé Láoyè nílùú Ogbomoso ti sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ ilé ẹjọ́ tó rọ Sọ̀ún Ogbomoso, Ọba Ghandi Olaoye lóyè gẹ́gẹ́ bíi Sọ̀ún tuntun.

Nínú atẹjade tí akọ̀wé ìdílé náà, Ọmọọba Saka Olabode Olaoye fi léde fún àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá ṣàpèjúwe ìdájọ́ náà gẹgẹ bí ohun tó wú ni lórí púpọ̀, tó sì ti dá ogo àti orúkọ rere ìdílé náà padà.

Ọláoyè ní ìdájọ́ tó wáyé kò jẹ́ ohun tuntun, tó sì tún kan sáárá sí adájọ́ K.A Adedokun fún bí ó ṣe rí i pé ìdájọ́ òdodo wáyé lórí ìyanisípò Sọ̀ún Ogbomoso.

Àtẹ̀jáde náà ní “Yíyọ Pásítọ Ghandi nípò ti dá ògo, iyì àti orúkọ rere ìdílé wa padà, inú wa sì dùn sí i.
Ìdájọ́ yìí kò kí ń ṣe ohun tó jọ Pásítọ̀ Ghandi lójú tàbí yà á lẹ́nu.

“Ohun tí kò yé wa ni bó ṣe kùnà láti tẹlé àṣẹ ilé ẹjọ́ àti ìdí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe súré láti kéde rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ṣaájú kí ìdájọ́ náà tó wáyé .”

Ìdílé Olaoye tẹ̀síwájú pé gbogbo ìrètí àwọn ni pé ẹnikẹ́ni tó bá ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lókè òkun ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà yẹ kó ṣe àpónlé fún ilé ẹjọ́ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn.

Ó wá fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìdílé Ọláoyè kò ṣetán láti tako àṣẹ ilé-ẹjọ́ tó gbé kalẹ̀ lórí ọmọ ìdílé àwọn.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here