IIé-ẹjọ́ tó ga jù lọ tèsíwájú lórí àwọn ẹ̀sùn tuntun t’Atiku fi kan Tinubu
Ọrẹ Òtítọ́jù
Ṣé wọ́n ní bí ọ̀rọ̀ ńlá kò bá tíì tán,èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé n lọ̀rọ̀ dà báyìí
Bí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ṣe ń fojú sọ́nà, tí gbogbo inú kóòtù sì pa rọrọ láti gbọ́ ibi tí ìdájọ́ yóó forí sọ lórí ẹjọ́ kò-tẹ́-mi-lọ́rùn tí Alaaji Atiku Abubakar, olùdíje fúnpò Ààrẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP), nínú ètò ìdìbò gbogbogboo tó wáyé lóṣù Kejì, ọdún 2023 yìí, pè ta ko Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, láti ẹgbẹ́ All Progressives Congress (APC), síwájú ilé-ẹjọ́ tó ga jù lọ nílẹ̀ wa, to wa niluu Abuja, àwọn adájọ́ náà ti gbé ìpinnu wọ́n kalẹ̀, wọ́n láwọn kò tí ì lè ṣe ìdájọ́ ojú-ẹsẹ̀ lórí atótónu àti àwíjàre olùpẹ̀jọ́ àti olùjẹ́jọ́, pàápàá lórí ẹ̀bẹ̀ tí Atiku tún bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n gba àwọn ẹ̀sùn tuntun tóun lọ̀ọ́ gbà nílẹ̀ Amẹ́ríkà lòdì sí Tinubu wọlé, wọ́n láwọn yóó gbé ìdájọ́ àwọn kalẹ̀ tó bá yá.
Eyi waye nigba ti Onidaajọ Inyang Okoro n ka ipinnu igbimọ onidaajọ naa sawọn eeyan leti lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtalelogun, yii.
Ṣaaju lawọn adajọ naa ti kọkọ ke si awọn lọọya to ṣoju ọkọọkan olupẹjọ ati olujẹjọ lati yẹ iwe ẹsun ati awijare koowa wọn, eyi ti igbimọ to n gbọ awuyewuye lori ẹsun to su yọ nibi idibo aarẹ, iyẹn Presidential Election Petition Tiribunal to ti kọkọ ṣedajọ lori ẹjọ naa fi ṣọwọ si wọn.
Wọn si ni ki awọn lọọya naa buwọ luwe lati fara mọ alaye, awijare ati atotonu koowa wọn, boya o peye, eyi ti ọkọọkan wọn ṣe bẹẹ.
Awọn adajọ naa tun tẹti bẹlẹjẹ si ẹbẹ pataki kan ti Amofin agba Chris Uche, to jẹ agbẹjọro Atiku Abubakar bẹ ọba awọn kootu naa pe ki wọn tẹwọ gba awọn ẹsun tuntun toun ko wa, eyi to da lori bi wọn ṣe ni Tinubu yiwee, o ṣe ayederu sabukeeti, o si purọ labẹ ibura.
O lonibaara oun rọ ile-ẹjọ lati wo awọn ẹsun ati ẹri wọnyi, ki wọn wo bo ṣe tẹwọn to, ki wọn si ṣedajọ ododo. O ni adura onibaara oun, iyẹn Atiku, ni pe kile-ẹjọ giga ju lọ yẹ aga mọ ọn nidii, ki wọn si da a lẹbi, pe ko kunju oṣuwọn lati waa dije tabi wa nipo aarẹ.
Àmọ́, isọrọ-nigbesi, loju-ẹsẹ lawọn lọọya olujẹjọ, ìyẹn Amofin àgbà Abubakar Mahmoud, to ṣoju fún àjọ elétò ìdìbò ilẹ wa, Independent National Electoral Commission (INEC), ati Amofin àgbà, Olóyè Wọle Ọlanipẹkun, tó ṣojú fún Ààrẹ Bọla Tinubu, àti Amofin àgbà Akin Olujimi, tóun dúró fún ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC, ti nawọ soke, ti wọn si ta ko ẹbẹ Atiku, wọn ni kile-ẹjọ naa ma ṣe gba awọn ẹsun tuntun wọnyi wọle, tori ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ, ti ko si nitumọ ni. Eyi lawọn agbẹjọro naa ṣe fa-n-fa-a mọ ara wọn lọwọ tile-ẹjọ náà fi lọ fún ìsinmi ráńpẹ́.
- Nígbà tíjokòó bẹ̀rẹ̀ padà, àwọn adájọ́ ọ̀hún fẹnu kò pé àwọn máa lọ̀ọ́ yiiri gbogbo ẹ̀bẹ̀ àti àwíjàre wọ̀nyí wò, àwọn yóó sì gbé ìdájọ́ kalẹ̀ tó bá yá.