Ìwé – Ẹ̀rí Tinúubú: Àtíkù kìí ṣe èèyàn dáadáa o – Tèmítópẹ́ Àjàyí
Fẹ́mi Akínṣọlá/Nurudeen Ridwan
Àwọn àgbà bọ̀ wọ́n ní bọ́rọ̀ ńlá kò bá tíì tán,èèyàn ńlá kò ní-ín sinmi àròyé.
Olùdámọ̀ràn pàtàkì lórí ètò ìròyìn sí Ààrẹ Bọ́lá Ahmed Tinúubú, ọ̀gbẹ́ni Tèmítọ́pẹ́ Àjàyí, ti bẹnu àtẹ́ lu igbákejì olórí orílèèdé yìí tẹ́lẹ̀rí, Àláájì Àtíkù Àbúbákà, fún bó ṣe tẹpẹlẹ mọ́ gbígba ìwé-èrí Tinúubú jáde ní ilé ìwé fásítì Chicago( CSU), nílẹ̀ Àmẹ́ríkà, látàrí àwọn ìwádìí ìjìnlẹ̀ àti àṣírí kan tó n wá. Àjàyí ní ìwà tí Àtíkù hù náà kòdára tó, kìí sì ṣe èèyàn dáadáa rárá.
lójú òpó ayélujára ìkànì abẹ́yẹ fò bí Àsá(túítà) rẹ̀ lọkùnri náà ti sọ̀rọ̀ ọ̀hún lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun , ọjọ́ kẹta, oṣù kẹsàn-án, ọdún yìí.
Tèmítọ́pẹ́ kọọ́ síbẹ̀ pèé: Ní tèmi o, ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí kọjá boyá Ààrẹ Tinúubú gboyè jáde ní fásitì chicago tàbí ko ṣe bẹ́ẹ̀. òótọ́ tó wà ni pé igbákejì Ààrẹ àná, Àtíkù kìí ṣe eku ire.
“kó dàá kéèyàn yẹpẹrẹ ọ̀rẹ́ rẹ̀, tàbí wọ́ọ nílẹ̀ ní gbangba bíi irú èyí tí Àtíkù ṣe fún Ààfẹ Tinúubú yìí, nítorí ipò ayé lásán, àti ìdíje fún ipò àṣẹ.
Tinúbú tà á n sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí , kò sóhun tí ṣe tán láti ran Àtíkù lọ́wọ́ sẹ́yìn . Tinúubú tó dáṣọ iyì bo Àtíkù, tó tún pèṣè ibùgbé fún un lásìkò tí Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ àti ẹgbẹ́ ọ̀ṣèlú PDP rẹ̀ nàá lẹ́gba, tí wọ́n tún ja sí ìhòhò nídìí oṣèlú lọ́dún 2007.
“kó dàá kí ọ̀rẹ́ kan sọ ara rẹ̀ di aléni mádẹ̀yìn gẹ́gẹ́ báwọn Èkìtì ṣe máa n sọ, bíí irú èyí tí Àtíkù ṣe yìí, kò sídìí tó fi yẹ bẹ́ẹ̀.
Ó tún ní, “kí lo fẹ́ẹ́ tìdí ìtọpinpin àtọkudórógbó yìí jáde gan an? ìmúlè mófo lásán ni” bẹ́ẹ̀ lọkùnrin náà sọ.
Àmòó lójú ẹṣẹ̀ làwọn kan tí n fèsì sọ̀rọ̀ ọ̀hún . Bí wọn ṣe n sọ pé ni tòdodo , kò dáa kéèyàn finú han ọ̀rẹ́, wọn ní o ti méjì inú àwọn ọ̀rẹ́ ìmùlẹ́ Tinúubú báyìí tí wọ́n tẹ́nbẹ́lú ẹ̀ ní gbangba, bẹ́ẹ̀ làwọn mí ìn n sọ pé ìwà yíyíwèé àti irọ́ pípa lábẹ́ ọ̀fin kò dáa rárá.
Ẹ ò rántí pé lẹ́yẹ ọ̀ sọkà táwọn ìwé ẹ́rí Ààrẹ Bọ́lá Tinúubú ti tẹ Àtíkù lọ́wọ́ l’Amẹ́ríkà làwọn àṣírí kan ti bẹ̀rẹ̀ sìí tú jáde pé Tinúubú yíwèé, wọ́n ló ṣe ayédèrú ìwé- ẹ̀rí Fásitì Chicago tó lọni, bẹ́ẹ̀ ló parọ́ iléèwé gírámà tó lọ.
Bákan náà ló jẹ́ pé àrọ̀nì ò wálé oníkòyí ò sinmi ogun í lọ ni Àtíkù fi ọ̀rọ̀ gbígba àwọn ìwé-ẹ̀rí náà ṣe nínú ẹjọ́ tó pè l’Amíríkà, bẹ́ẹ̀ ni dẹ̀yìn lóríàrọwà táwọn kan pá fún un pé kó jáwọ́ nínú wíwá fín-ín ìdí kókó sábúkéètì Tinúubú.