Tí ìgbéyàwó re̩ bá kùnà, wàá dá owó mi padà -Cubana Chief Priest

Tí ìgbéyàwó re̩ bá kùnà, wàá dá owó mi padà -Cubana Chief Priest

Mary Fágbohùn

Gbajumo oloti Naijiria Pascal Chibuike Okechukwu, ti a mo si Cubana Chiefpriest ti safihan pe to ba wu tokotaya kan lati pinya, won gbodo san owo ti oun na ni ojo igbeyawo won pada fun oun.

Cubana Chief Priest so eyi di mimo ninu atejade kan to fi lede lori Instagram ni ojo Isegun.

O so pe saaju ki tokotaya to pinnu lati pinya, won gbodo gbiyanju lati wo iranlowo owo ti awon eniyan se fun won ni ojo igbeyawo won.

Cubana tesiwaju wi pe ti won ba pe oun si ibi igbeyawo, tokotaya naa yoo fi owo si iwe lati seleri pe won yoo san owo fun oun pada ti oro won ko ba wo mo.

O wi pe, “Saaju ki e to pinya e gbiyanju lati wo Owo/Akoko/Agbara ti a fi dokowo si inu igbeyawo yin.

“Ni itesiwaju ti o ba pe mi fun igbeyawo a maa jo ni adehun pe ti igbeyawo yin ba fe baje e maa da owo mi pada.