Kàyéfì! ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn pa DPO, wọ́n gé orí àti nǹkan ọmọkùnrin rẹ̀
Fẹ́mi Akínṣọlá
À ki á máa ṣàdúrà kí á mórí délé, lẹ́nú ìgbésẹ̀ ìrìnàjò wa gbogbo.Kàyééfì gbá à ló jẹ́ bí àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ṣekupa DPO ọlọ́pàá kan, Bako Amgbanshin, níìpínlẹ̀ Rivers, ti wọ́n sì ṣe òkú rẹ̀ báṣubàṣu.
Ìròyìn ní ṣe ni àwọn agbégbọn náà dènà dé ọlọ́pàá náà àtàwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń bọ̀ láti ibi tí wọ́n ti lọ tọpinpin àwọn ọ̀daràn kan lágbègbè Ahoada.
Gẹ́gẹ́ bíi ohun tí a gbọ́, ṣe làwọn agbebọn náà ṣíná ìbọn bolẹ ní kété tí wọ́n fojú ganni ọlọ́pàá ọ̀hún àtàwọn tó wà pẹlu rẹ̀, tí iro ìbọn sí dún lákọlákọ́.
Ó ṣojú mi kòro kan tí kò fẹ́ fi orúkọ rẹ̀ lédè ṣàlàyé pé “Wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún ara wọn ní kété tí àwọn ọmọ DPO náà àtàwọn ọmọ Iceland ti 2baba kó sọdi rí ara wọn títí tí ọta fi tán nínú ìbọn wọn.”
A gbọ́ pé olóògbé náà dúró digbí bí ìró ìbọn náà ṣe ń dún lákọlákọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ yòkú na pápá bora .
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni ọwọ́ àwọn afurasí ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tẹ DPO ọ̀hún, tí wọ́n sì mú láàyè.
Fídíò kan tó gba orí ayélujára ṣàfihàn orí àti nǹkan ọmọkùnrin olóògbé náà tí àwọn afurasí fi ń ṣe ẹlẹ́yà lẹ́yìn tí wọ́n gé e tán .
Nínú fídíò ọ̀hún ni ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà ti ń sọ pé “DPO ṣé ìwọ nìyẹn… kí ló ń ṣẹlẹ̀… ìwọ lo láyà láti gbéná wojú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Iceland.”
Ẹ̀wẹ̀, alukoro iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Rivers, Grace Iringe-Koko, ti sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá àwọn nínú jẹ́ gidi, àti pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ṣọ̀fọ̀ olóògbé ọ̀hún.
Nínú àtẹ̀jáde kan lójú òpó abẹ́yẹfò rẹ̀, iléeṣẹ́ náà sọ pé àwọn kò ní sinmi títí tí ọwọ́ yóó fi tẹ́ gbogbo àwọn tó lọ́wọ́ nínú ikú olóògbé ọ̀hún.
Ó pari àtẹ̀jáde náà pé olóògbè ọ̀hún jẹ́ akínkanjú agbófinró tó gbógun ti ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Rivers saájú ikú rẹ̀.