‘Naijiria ń bà mi lọ́kàn jẹ́ lójoojúmọ́’ – Olórin, Simi figbe ta

‘Naijiria ń bà mi lọ́kàn jẹ́ lójoojúmọ́’ – Olórin, Simi figbe ta

 

Mary Fágbohùn

 

Gbajumo olorin, Simisola Kosoko, ti a mo si Simi, ti kedun bi eto oro aje se je nnkan to n le koko si ni orile ede yi.

 

O so pe ipo ti Naijiria wa n ba oun “lokan je diedie si lojoojumo.”

 

Olorin Duduke naa woye bi awon omo Naijiria se n farada ipo irukosi eto oro aje to wa nita yi.

 

Lori Twitter re ni ale Ojoru, o ko o pe, “Naijiria n ba okan mi je diedie si lojoojumo. Bawo ni awon eniyan se n laa ja?”

 

E ranti pe owo epo n goboi si lati igba ti Aare Bola Tinubu ti yo owo iranwo lori epo.

 

Ni titele eyi, iye owo ounje ati awon nnkan ti awon eniyan fi gbe igbe aye irorun lapapo goke sii kaakiri orile ede.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here