Ìrònú dorí àgbà kodò’ Emefiele búsẹ́kú ní kóòtù,

Ìrònú dorí àgbà kodò’ Emefiele búsẹ́kú ní kóòtù,

Ọrẹ Òtítọ́jù

Yooba bọ̀, wọ́n lọrọ tó bá mú kí àgbàlagbà máa làágùn yọbọ lábẹ́ òrùlé, ẹkùn làgbà ọ̀hún ń sun, àmọ́ ní ti ọrọ̀ Ọgá àgbà bánkì àpapọ̀ ilẹ̀ wa, CBN, ti wọ́n yọ nípò, Godwin Emefiele, to si n káwọ́ pọ̀nyìn rojọ lórí àwọn ẹsùn kan tí wọ́n fi kàn án, ọ̀rọ̀ ọkùnrin náà kọjá kí àgbàlagbà máa làágùn o, níṣe ni bàbá ọ̀hún bú sẹ́kún kíkorò ní kóòtù, tó ń wa ẹkùn mu bíi kà-à-sí nǹkan.

Iṣẹlẹ to ṣeeyan laaanu yii waye l’Ọ́jọ́bọ, ọjọ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹjọ yìí, lásìkò ti wọn tún fojú Emefiele balé-ẹjọ́ gíga ilú Abuja, lolu-ilu ilẹ wa, amọ ti ẹjọ rẹ ko le tẹsiwaju, ti ireti ati atotonu Emefiele lati kuro lahaamọ awọn agbofinro tun ja si pabo. Niṣe ladajọ ni ọsẹ to n bọ, iyẹn Ọjọruu, ọjọ́ kẹtadinlogun, oṣù Kẹjọ yìí, ni kí wọ́n tún mú olujẹjọ yìí wá síwájú òun, ó ní kí wọ́n ṣì dá a padà sakolo àwọn ẹṣọ́ ọtẹlẹmuyẹ àpapọ̀ ilẹ̀ wa, Department of State Service (DSS). Bí Emefiele ṣe gbọ́ àṣẹ tadajọ pa yìí lọkunrin náà dorikodo, ó bu sẹkun gbaragada ni.

Ohun to mu ki idena ba igbẹjọ rẹ lori awọn ẹsun tuntun tijọba ṣẹṣẹ fi kan an, eyi to da lori igbimọ-pọ lati huwa ibajẹ, kiko owo jẹ ni koto ọba, ṣiṣẹ owo ilu mọkumọku ati iwa jibiti lilu, ti ẹjọ naa ko fi tẹsiwaju ni pe ọkan lara awọn ti wọn jọ fẹsun iwa ọdaran yii kan, Sa’adatu Yaro, ko le yọju si kootu. Emefiele, Yaro ati ileeṣẹ kan bayii nijọba ni wọn lọwọ ninu ẹsun ti wọn fi kan wọn naa.

Lara ẹsun ti wọn we mọ Emefiele lẹsẹ ni pe o fi owo ilu ṣe jẹ-ki-n-jẹ pẹlu Yaro, ti wọn ni ọga agba kan loun ni tiẹ nileeṣẹ kan ti wọn fi wọ obitibiti owo jade lasunwọn banki apapọ loṣu kẹrin, ọdun 2016, wọn lowo ọhun n lọ bii biliọnu meje Naira (N6.9b).

Bi wọn ṣe kawe ẹsun yii atawọn mi-in si Emefiele leti tan, ni adajọ beere pe awọn olujẹjọ gbogbo da, wọn ni Emefiele nikan lawọn ri mu wa, niṣe ni Adajọ Hamza Muazu bẹrẹ si i kọwe wẹrẹwẹrẹ kan, lẹyin naa lo kede pe igbẹjọ ko le tẹsiwaju, tori ẹsẹ olujẹjọ ko pe, lo ba paṣẹ ki wọn da Emefiele pada sibi ti wọn ti mu un wa.

Gbogbo alaye ti lọọya rẹ fẹẹ ṣe lati bẹbẹ iyọnda aaye tabi beeli fun onibaara rẹ ni ko ṣee ṣe, tori bi adajọ ṣe paṣẹ tan ni wọn pariwo, “kọọtu”, ti adajọ naa si dide lori aga wọle lọ.

Bóyá ti pé o kéré tán, Emefiele yóò tún lo ọsẹ kan gbáko sí lákolo àwọn DSS yìí ló pa bàbá náà nígbe ni o, bóyá tí igbẹjọ tí kò sì lè tẹ̀síwájú ni, a ò mọ, àmọ́ àwọn àgbà bọ̀, wọ́n ní àròkàn ní í fa ẹkún àsun-ì-dá wá.

Ẹ ó rántí pé ó ti lé lósù kan báyìí tí Emefiele ti ń pààrà kóòtù, tí kò sì tí lè fàtàrí lé pílò nínú ilé rẹ̀, àkàtà àwọn DSS ló ń bá dé kóòtù, ibẹ̀ náà ló sì ń padà sí, lórí àwọn ẹsùn ọlọkan-o-jọkan tí wọ́n fi kan ọgá àgbà àwọn báńkì ilẹ̀ wa náà, Central Bank of Nigeria.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here