IROYIN ALARIYA LATI INU IROYIN OWURO
Mo so fun Omotola pe ko gbodo maa fi gbogbo enu kiisi ninu fiimu – Baale Omotola, Mathew Ekeinde
Baale gbajugbaja osere fiimu, Omotola Jalaade-Ekeinde, ti soro lori iha to ko si ipa ti iyawo re maa n ko ninu awon ere naa.
Okunrin naa ti oruko re n je Matthew Ekeinde, ni ara kii ta oun nigba ti iyawo oun ba n fenu ko okunrin lenu ninu fiimu, tori oun mo pe ere ni won n se, kii se otito.
Bakan naa, Alagba Matthew, eni to je awako baaluu ti won n pe ni pilot, so pe oun tun mo pe lopolopo igba ti awon osere fiimu ba n se bi eni gbe enu si ara won lenu, won kan maa fie nu kan enu ni, eyi ti a mo si pecking. O ni won kii je ete bi awon ololufe gidi se maa n se e – eyi ti a mo si kissing.
Sugbon sa o, bale Omotola naa jewo pe okunrin ni oun, ti ko ni fe ki eni Kankan koja aaye re lodo iyawo oun, ti ko si ni fe ki obinrin naa tae se agere.
O ni oun jerii Omotola pe kafinta re ko gbodo jesoo. O ni oun ti kilo fun un pe ko gbodo se igbenu bo enu bi igba ti lokolaya ba n se e.
Ninu iforowanilenuwo kan ni Alagba Matthew ti so oro yii. Ninu iforowanilenuwo naa pelu iwe iroyin alatagba kan to n je kemiashefonlovehavens, Omotola naa se alaye iri re ninu igbeyawo won. O ni oko oun je eni kan to nifee oun denu, to se atileyin fun oun, to si je pe o lakikanju.
O ni loooto, Olorun lo n joba ninu igbeyawo naa, tori ko si ajosepo ti kii ni konu-n-oho lekookan.
O ni bi awn ba ni gbolohun aso, oun ni oun koko maa n be bale oun.