Àìsòótó̩: Kò sí e̩ni tí o̩wó̩ ré̩ mó̩ – Osere tiata Yul Edochie sò̩rò̩ sí àwo̩n alágàbàgebè
Mary Fágbohùn
Alariyanjiyan osere tiata Naijiria, Yul Edochie ti soro lori isoro aisooto to n lo kaakiri ni ile-ise alarinrin Naijiria.
E ranti pe awon olorin meji Banky W ati Davido ni won fi esun aisooto kan.
Nigba to n fesi, Edochie eni ti awon eniyan n da lebi fun fife iyawo keji ni ibere odun yi, so pe opolopo fi isoro ti won ni ninu igbeyawo won pamo bee ni won si n da oun lejo.
Nigba to n tabuku iwa agabagebe awon ilumooka miran, osere naa so pe ko si eni to pe.
Ninu atejade kan lori Instagram laipe yi, o ko o pe; “Ko si eni to dara ju. Ko si eni to mo ju. Onikaluku kan n fi tiwon pamo ni, won kan n da mi lejo ni.”