Ilumomika onifiimu Noliwuudu kan, Tonto Dikeh, ti muni ranti itan kan ninu ALAWIYE YORUBA, ti Oloogbe J.F. Odunjo ko, ti gbogbo eniyan maa n ka ni ile iwe alakobere nigba kan.
Ninu itan naa ni eye asa ti huwa buruku, to gbe omo adie arabinrin kan ti oruko re n je Tola lo.
Nigba to n se alaye bi oro naa se ka omo naa lara, asotan ni, ‘O ma se o, asa gbe omodie Tola lo.’
Ohun to sele ni pe bi o tile je pe asa ko gbe adie Tonto Dikeh lo, agbara ojo se oko adie – iyen poultry farm – re lose ni ojo die seyin.
Opo eniyan ko mo pe Tonto Dikeh ni ogba adie.
Sugbon ninu akosile kan lori ero ayelujara lojo die seyin, o se alaye bi ojo alarooda kan se ya lu oko adie oun naa, to si gbe egberin (800) awon adie oun lo.
O ni oro naa dun oun wonu egungun.
Afi ki Olorun dun un ninu, ko di i fun un ni ona miran.
Ti a ko ba gbagbe, Tonto Dikeh je osere fiimu ti awuyewuye saaba maa n sere lori orule ile re.
Oun naa si ti wa ninu oselu bayii, to n se olubadije fun ipo gomina ni Ipinle Rivers.