Gbogbo iṣẹ́ Arẹgbẹṣọla tí Oyetọla pa tì ni mo máa ṣe – Adeleke

Gbogbo iṣẹ́ Arẹgbẹṣọla tí Oyetọla pa tì ni mo máa ṣe – Adeleke

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣu6n, Sẹ́nátọ̀ Ademọla Adeleke, ti sọ pé gbogbo àwọn iṣẹ́ àkànṣe tíjọba Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹgbẹṣọla dáwọ lé, èyí tó sì yẹ kí ìjọba Alhaji Gboyega Oyetọla parí, ṣùgbọ́n tí kò ṣe, lòun yóò ṣe láṣeyọrí.

O ni lara awọn nnkan ti oun ṣeleri fun awọn araalu lasiko ipolongo ibo oun ni pe oun ko ni i pa iṣẹ kankan ti, oun si ti bẹrẹ igbesẹ lori awọn iṣẹ naa.

Nibi eto siṣi ọfiisi iwe irinna, pasipọọtu, eyi tileeṣẹ ọrọ abẹle lorileede yii, labẹ Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla, kọ siluu Ileṣa, to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Adeleke ti sọ pe bi awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ṣe fẹran Arẹgbẹṣọla nigba to jẹ gomina naa ni wọn ṣe fẹran oun naa bayii.

O ni, “Ẹgbẹ oṣelu yoowu ti o ba wa, ti o ba ti ri nnkan itẹsiwaju, o gbọdọ tẹsiwaju ninu ẹ. Ẹni ti awọn araalu feran ni Arẹgbẹṣọla, mo maa tẹsiwaju ninu awọn iṣẹ rere to ṣe silẹ l’Ọṣun”.

Gomina Adeleke waa fi da Arẹgbẹṣọla loju pe ipinlẹ rẹ ni ipinlẹ Ọṣun, ko si si ẹnikankan to le le e nibẹ. O ni oun yoo ko lọ sinu ile ijọba laipẹ, iyẹn ti oun ba ti ṣe awọn atunṣe ibẹ tan, koda, Arẹgbẹṣọla ni yoo ṣi ile naa fun oun.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla dupẹ lọwọ Gomina Adeleke fun apọnle to fun un nipa kiko gbogbo awọn abẹṣinkawọ rẹ wa sibi eto naa niluu Ileṣa, lai sẹ pe awọn jọ jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa.

O ṣalaye pe ọfiisi naa wa lati ran awọn ọfiisi ti wọn ti n ṣeto iwe irinna to wa kaakiri lọwọ ni, o ni wọn yoo maa ya fọto nibẹ, wọn yoo si maa gba akọsilẹ awọn to ba nilo iwe irinna silẹ nibẹ lati mu ki igbesẹ naa tubọ ya kiakia si i.

Arẹgbẹṣọla rọ àwọn òṣìṣẹ́ àjọ iwọle-wọde àwọn àjèjì láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, láti lè fòpin sí ìwọlé wọde àwọn àjèjì latawọn orílẹ-èdè míràn wá sínú ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here