Àwọn márùn-ún tó ń ta ẹ̀yà ara èèyàn kó sí gbaga ọlọ́pàá
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn oníwààbàjẹ́ ò dákẹ́, bẹ́ẹ̀,iléeṣẹ́ ọlọ́pàá náà kò káààrẹ̀ látí ṣẹ́bùrú u wọn.
Iléèeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti nawọ́ gán àwọn afurasí márùn-ún kan tí wọ́n fura sí pé wọn jẹ́ àwọn tí wọ́n máa ń lo ẹ̀yà ara ènìyàn fi ṣe oògùn owó.
Wọ́n ní àwọn márùn-ún yìí máa ń hú òkú ní itẹ́ òkú tí wọ́n sì máa ń ta ẹ̀yà ara wọn fún àwọn tó máa ń lò ó fún oògùn owó.
Àwọn afurasí náà ni Oshole Fayemi, Oseni Adesanya, Ismaila Seidu, Oseni Oluwasegun àti Lawal Olaiya.
Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kejìlá ọdún 2023 ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà.
Oyeyemi ní ọwọ́ tẹ àwọn afurasí náà lẹ́yìn tí àwọn kan wá fi ìròyìn náà tó àgọ́ ọlọ́pàá Odogbolu létí pé àwọn afurasí náà ń gbèrò láti lọ hú òkú níbì kan.
Ó ní àwọn afurasí náà ló wà nídìí híhú òkú káàkiri agbègbè Ososa, ìjọba ìbílẹ̀ Odogbolu, tí wọ́n sì máa ń yọ ẹ̀yà ara àwọn òkú tí wọ́n bá hú náà tà.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn afurasí náà ló ti jẹ́wọ́ pé àwọn ló wà nídìí híhú àwọn òkú náà.
Bákan náà lọ ní wọ́n ti tún jẹ́wọ́ pé àwọn máa ń ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún àwọn tó máa ń lò wọ́n láti fi ṣe ètùtù ọlà.
“Nígbà tí ọ̀gá ọlọ́pàá àgọ́ Odogbolu gbọ́ sí ìròyìn náà pé àwọn afurasí yìí tún fẹ́ lọ ṣọṣẹ́ ló da àwọn ọlọ́pàá síta láti fi kélé òfin gbé wọn.”
Oyeyemi tẹ̀síwájú pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Frank Mba ti darí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwádìí ìwà ọ̀daràn láti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ó ní lẹ́yìn ìwádìí ni àwọn afurasí náà yóò fojú ba ilé ẹjọ́ fún ìjìyà tó yẹ.