Peter Obi sàbè̩wò sí obìnrin tí wó̩n gún lójú l’ó̩jó̩ ìdìbò

Peter Obi sàbè̩wò sí obìnrin tí wó̩n gún lójú l’ó̩jó̩ ìdìbò

Mary Fágbohùn

Oludije fun ipo are ninu egbe oselu Labour Party, Peter Obi ti sabewo si Jennifer Efidi, obinrin ti awon janduku gun ni oju nibi eto idibo yan are ati omole igbimo asoju.

Efidi ni won gun loju nigba to fe dibo ni agbegbe Surulere, ipinle Eko.

Obi fi aworan ibewo re si obinrin naa lede ni oju opo Twitter ni ojo Aje.

O ko o wi pe, “Loni, mo se ibewo si arabinrin Jennifer Efidi. Eni ti won se akolu si ni ojo karun-din-ni-ogun osu keji ni ona lati se idena fun n ko ma ba a dibo, sugbon o duro lori ese re. Jennifer je akoni fun ijoba awarawa ni Naijiria.

“O je ona kan ti ma a fi toka si gbogbo awon omo Naijiria ti won jiya ni iru ona yii nigba ti won n gbiyanju lati se ojuse won gegebi oludibo lati le e lowo si mimu Naijiria tuntun jade. Bi opolopo awon omo Naijiria miiran, mo gboriyin fun iwa igboya ati ipinnu re. Jennifer je afihan igboya nitooto fun Naijiria tuntun.”

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here