Obasa fi o̩kàn ará ìlú balè̩ lórí ìjo̩ba ìbíle̩ LCDA

Obasa fi o̩kàn ará ìlú balè̩ lórí ìjo̩ba ìbíle̩ LCDA

O̩láyínká Àlàbí

Abenugan Ile Igbimo Asofin Ipinle Eko, Onarebu Agba Mudasiru Obasa, ti fi okan awon eniyan bale pe awon ijoba ibile Local Council Development Areas ko lo si ibi kankan o.

Alagba Obasa ni awon asofin Ipinle Eko ko ni da awon LCDA naa nu.

Dipo bee, o ni awon yoo se ofin ti yoo tubo ro won ni agbara ni.

Abenugan naa so eyi leyin ti ominu bere si ko opo eniyan, nigba ti Ile Igbimo Asofin naa bere ayewo ofin to de awon LCDA naa.

Awon asofin naa bere eyi leyin ti ile ejo to ga julo , iyen Supreme Court, gbe ofin kale pe owo to n bo lati Abuja, eyi to je ti awon ijoba ibile, gbodo maa lo si apo won taara ni.

Ile ejo agba naa fi ofin de awon ijoba ipinle pe won ko gbodo f’owo kan owo ijoba ibile naa mo.

Latari eyi, Obasa atii awon eniyan re wa n gbe igbese lati ri i pe iya ko je awon ijoba ibile LCDA naa.

Abenugan naa ni leyin pe awon yoo ri i pe awon LCDA naa ko di atemere, awon yoo gbe igbese lori bi Ile Igbimo Asofin Apapo (National Assembly) yoo se so won di ijoba ibile gbogi.

O ranti pe Ipinle Kano ni ijoba ibile merinlelogoji (44), ti Eko si ni ogun (20) pere.

Ninu ero Obasa, ko si bi aja se se ori ti obo ko se.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here