Terry Apala kérora pé àìlówó ń s̩e àkóbá fún is̩é̩ orin òun
Mary Fágbohùn
Olorin Naijiria, Terry Apala, ti so pe a ti ri owo na si orin je adojuko nla kan ti ise re n koju.
Apala so eyi di mimo lori eto kan laipe yi nibi ti o ti se asaro lori orisiirisii nnkan nipa ise orin re.
“Adojuko mi ti o tobi ju bayii ni owo. Mo ro pe mo ni gbogbo nnkan, mo ni gbogbo nnkan ti yoo gba mi lati de ipele agbaye, lati ri itewogba kaakiri sugbon adojuko nla mi ni owo.”
“Mo ki awon Wizkid FC ti won duro ti mi, mo ki DJ Tunez ati Seyi Vibes. Mo n ri ipa awon Gen Z ninu ise mi lati igba ti Wizkid Fc ti fi atejade kan lede nipa mi.”
Apala, eni ti orin re pelu Wizkid so di eni ti aye mo, tun so di mimo pe yoo je iyi lati ko orin pelu Davido.
“Ti Davido ba le pe mi bayii, maa se lesekese. Mo ti wa Davido bi igba meta sugbon ko tii sele, o si ye mi pe gbogbo eniyan ni owo won di. Ti Burna Boy ba pe mi fun igbasile iseju kan, mo de tan.
“Mo ti wa Olamide, o si ti da mi lohun. Mo fi orin kan ranse si.”
Nigba to n soro lori bi orin to ko pelu Wizkid se jade, o wi pe “Mo je ore DJ Tunez lati 2018 sugbon a pade ni 2023 a si jo soro nipa awon orin kan. Ni ojo kan, o so pe oun ni iyalenu kan fun mi, mo ro pe owo ni nitori pe o sunmo ojo ibi mi, o pe mi o so pe Terry wo oju awe Whatsapp re, si iyalenu mi mo gbo ohun Wizkid ninu orin mi”, o fikun un.