Mercy Aigbe jé̩rìí sí àdéhùn ìgbéyàwó Priscilla Ojo pè̩lú olórin Tanzania

Mercy Aigbe jé̩rìí sí àdéhùn ìgbéyàwó Priscilla Ojo pè̩lú olórin Tanzania

Mary Fágbohùn

Gbajumo osere tiata Naijiria, Mercy Aigbe, ti fi idi re mule pe omobinrin Iyabo Ojo ti se adehun igbeyawo pelu gbajugbaja olorin Tanzania, Juma Jux.

E ranti pe omobinrin Iyabo Ojo, Priscilla fi fonran oun ati Juma Jux lede ninu aso idana Naijiria, ni eyi to jo pe won ya aworan ti wo fe lo fun igbeyawo.

O fi oro ifori sori fonran naa pe “Ololufe mi”. Jux pelu fi fonran yi lede lori Instagram re.

Amo sa, leyin eyi, awuyewuye aheso oro igbeyawo jeyo lori ayelujara.

Nigba to fi idi adehun igbeyawo won mule, Mercy Aigbe ninu fonran kan to fi lede lori Instagram, ki Iyabo Ojo ku oriire, eni ti o je ore ati akegbe re.

Nigba ti o fi atejade Priscilla lede pelu, Aigbe fi idi re mule pe loooto won ti se adehun igbeyawo.

O ko o pe: “Bee ni! Won ti mu omobinrin mi. Ku oriire ife mi @its.priscy , ana wa @juma_jux a ki o kaabo pelu oyaya ati ife, a o fi omo wa sere o. Sugbon a jeri re.

“Ki eyin mejeeji tesiwaju lati maa gbile ninu alaafia, ayo, erin ati ibukun ti ko lopin. @iyaboojofespris ku oriire Ore, o se daadaa, mo n fi o yangan.”

Nigba to fesi si atejade Aigbe, Iyabo Ojo soro, o pe Mercy Aigbe ni ore iyawo.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here