Màá s̩e ìgbéyàwó – Tems
Onirawo olorin R&B, Temilade Openiyi, ti a mo si Tems, ti so pe aaye wa fun oun lati se igbeyawo.
Yato si awon ilumooka miran ti won fagile igbeyawo, olorin eni odun mokandinlogbon olugbafe eye Grammy naa so pe oun n reti lati ri ohun ti ojo iwaju ni fun oun.
Tems farahan lori eto ‘Shopping The Sneakers’ laipe yii.
Atokun eto naa beere pe, “Se wa a se igbeyawo ni ojo kan?”
Leyin asaro die, Tems dahun pe, “Bee ni. A o maa woo.”
Tems ni ko si eni to mo boya o wa ninu ibasepo ife kankan.
Aheso oro kan waye laipe yi pe o loyun fun asoro orin kiakia Amerika, Future, sugbon o so pe iro ni.
Ninu iforowero kan pelu oniforan YouTube kan, Korty EO, Tems so pe opolopo okunrin ni ko ni nnkan se ninu ibasepo yato si ibalopo.