Ilé-isé̩ orin wà lé̩yìn mi digbí – TG Omori

Ilé-isé̩ orin wà lé̩yìn mi digbí – TG Omori

Oludari fonran orin, TG Omori, ti soro lori bi awon kan se so pe awon ilumooka Naijiria ko se satileyin fun nigba ti o wa ni ipo ailera.

Omori, eni to sese se ise abe kindinrin laipe yi, salaye pe awon akegbe ati ore re n “satileyin fun lai dawo duro” ninu ailera re, saaju ki o to de etigbo gbogbo eniyan.

Ninu oro kan lori ayelujara, Omori safihan imoore fun adura, atileyin, ati ife ti o ri gba lasiko naa.

O ro awon eniyan lati mase wo ohun ti awon elomiran n so, o pe won ni “aja to n gbo fun okiki.”

Lori X re, o ko o pe: “Gbogbo nnkan ti mo nilo ni adura, atileyin, ati ife, mo si dupe pupo pe mo ri eyi gba ni ekunrere.

“Ile-ise yii ati awon ore mi wa leyin mi fun opolopo osu saaju ki o to di ohun ti gbogbo eniyan mo. E ma se gbo ti aja to n gbo fun okiki. Jesu loba.”

Esi Omori waye leyin ti Portable da awon ilumooka Naijiria lebi pe won ko lati da owo fun un, bi o tile je wi pe won feran lati ran awon miran lowo, bii Bobrisky.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here