Francisca Owumi ti jáde láyé

Francisca Owumi ti jáde láyé

Mary Fágbohùn

Irawo eto Elegbon Agba Naijiria teleri, Francisca Owumi, ti jade laye.

Onirawo eto naa jade laye leyin aisan ranpe.

Iroyin jade pe Francisca Owumi, eni to se ipo keji ninu abala akoko fun eto mohunmaworan Elegbon Agba Naijiria ni 2006, jade laye ni ojo kokandinlogbon osu kejo, 2024.

Nigba ti won n kede iku re lori ayelujara, awon ebi re ko o pe; “Omo wa ati arabinrin wa. Sun n re, Amin.”

Oloogbe Francisca, ti a mo fun ijo re, wa ninu ile pelu eni to jawe olubori ninu eto naa Katung Aduwak, Gideon Okeke, Ebuka Obi Uchendu, Maureen Osuji, ati awon miran.

Leyin eto naa, o wo ile ise orin Naijiria fun igba die pelu orin “Diva” ati “Gbadun You.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here