Bimbo Afolayan àti o̩ko̩ rè̩ sàjo̩yò̩ fún ilé tuntun
Osere tiata Bimbo Afolayan ti fi imoore ati ayo re han bi oun ati oko re, Okiki Afolayan, se n sajoyo fun ile tuntun.
Okiki fi iroyin naa lede lori Instagram, nigba to fi aworan ile to rewa naa lede, o ki oun ati ebi re ku oriire.
Lori Instagram re, Bimbo ti fi imolara re han, o wi pe oun ko fe fi atejade nipa ile naa lede.
O dupe lowo Olorun fun ibukun tuntun yi, o si fi imoore re han si oko re, eni ti o gbagbo pe Olorun lo yan fun oun.
“Mo se opolopo fonran lati fi lede sugbon ni gbogbo igba ti mo ba fe fi lede ni mo maa n so pe hmmmmm Olorun lo se eyi, Mo se fonran naa ki n to kuro ni Naijiria lo si Houston, oun ti o dun ju nibe ni: riri iyalenu Aliyah to rewa!
“Olorun lo le e se eyi. Bee ni, eyin ara, ibukun nla miran ti OLORUN fi kun un fun wa niyi. Okiki owon @okikiafolayan, OLORUN lo fi e fun mi, gbogbo igba ni ma maa fun OLORUN ni ogo”.