Wọ́n ti mú àwọn ọmọ Nàìjíríà yìí ní UK, ayédèrú ìwé erí ìgbéyàwó ni wọ́n ń ṣe
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ẹ̀wọ̀n ọdún gbọọrọ ni wọ́n ju àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà mẹ́rin kan sí nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì báyìí, ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan wọ́n ni pé wọ́n ń bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ayédèrú ìwé -ẹ̀rí ìgbéyàwó tí wọ́n fi ń gbé l’Óke Òkun.
Awọn afurasi ọdaran naa ni: Abraham Alade Ọlarotimi Onifade, ẹni ọdun mọkanlelogoji, Abayọmi Aderinsọla Shodipọ, ẹni ọdun mejidinlogoji, Nọsimọt Mojisọla Gbadamọsi, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Adekunle Kabir, ẹni ọdun mẹrinlelaaadọta.
A gbọ pe lati ọdun 2019 si 2023 ni awọn afurasi ọdaran naa fi ṣiṣẹ to lodi sofin ọhun, ti wọn si ti ba ẹgbẹrun meji awọn ọmọ orileede Naijiria ṣe ayederu iwe-ẹri igbeyawo lati fi wọ orileede Gẹẹsi lọna aitọ.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn ṣe idajọ wọn ni kootu kan ti wọn n pe ni Woolwich Crown Court, to wa nilẹ Gẹẹsi.
Agbegbe kan ti wọn n pe ni Gravesend, niluu Kent, lorileede Gẹẹsi ni Onifade n gbe, ilu Manchester, ni Shodipọ n gbe, nigba ti wọn ko darukọ adugbo tawọn meji yooku n gbe lasiko ti wọn foju wọn bale-ẹjọ naa laipẹ yii.
Ẹwọn ọdun mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara lọgba ẹwọn ni wọn ni ki wọn lọọ ṣe.