Pásítọ̀ Ogúnṣẹ́ tí wọ́n lóun àti ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́ nínú ikú akẹ́kọ̀ọ́ Kwara ni: ọmọ mi ló kọwọ́ mi bọ ṣọ̀ọ̀lọ̀

Pásítọ̀ Ogúnṣẹ́ tí wọ́n lóun àti ọmọ ẹ̀ lọ́wọ́ nínú ikú akẹ́kọ̀ọ́ Kwara ni: ọmọ mi ló kọwọ́ mi bọ ṣọ̀ọ̀lọ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá

L’ọ́jọ́ Ẹtì, ọgbọ̀ńjọ́, oṣù Kẹjọ, ọdún 2024 yìí, ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara, ṣàfihàn àwọn afurasí mẹ́fà kan, Pásítọ̀ Adebayọ Adeniyi bàbá, Adebayọ Joshua Happiness, tó jẹ́ ọmọ, Adeniyi Bukọla, tó jẹ́ ìyàwó pasitọ àtàwọn mẹta mìíràn: Adeoye Adeọla, Lawal Aminat àti Bulus Peter, tí wọ́n fẹ̀sùn kan pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin College of Health Technology, tìlú Ọffa, ìyẹn Awesu Mojiṣọla, tí wọ́n pa sí Òtẹ́ẹ̀lì Whitfield nílùú Ìlọrin.

Pasitọ Adebayọ Adeniyi, ni oun ko mọ nnkan kan nipa iku ọmọbinrin naa, ṣugbọn ohun toun le sọ ni pe ọmọ oun Joshua Happiness lo ko awọn sinu wahala, to si ki ọwọ awọn bọ sọọlọ.

Ninu ọrọ ti Happiness, o ni ọrẹbinrin oun ni Kọlawọle Timilẹyin, ti ajọsẹpọ to daa si wa laarin awọn mejeeji, ṣugbọn nitori pe ko raaye tẹle oun lọ s’Ilọrin, lati ilu Ọffa, ni o ṣe ṣeto ọrẹ rẹ, iyẹn Awesu Mojiṣọla.

O tẹsiwaju pe Mojiṣọla ko gba k’oun ba a ni ajọṣẹpọ ninu otẹẹli naa ni oun ṣe gba yara miiran pẹlu obinrin mi-ín, lati le tẹ ara oun lọrun, oun ko mọ ohunkóhun nipa iku Mojiṣọla.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni Kwara, Victor Ọlaiya, sọ pe iṣẹlẹ naa waye lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii, nigba ti Awesu Mojiṣọla gba ipe lati ọdọ Kọlawọle Timilẹyin, ti oun naa jẹ akẹkọọ-binrin ile-ẹkọ College of Health Technology, niluu Ọffa, nibi to ti n jisẹ Adebayọ Joshua Happiness, akẹkọọ Fasiti Summit, niluu Ọffa, fun un pe ki o tẹle ọmọkunrin naa lọ si ode ariya kan nileetura Whitefield, to wa niluu Ilọrin, yoo ṣe bii ọrẹbinrin rẹ, yoo si gba ẹgbẹrun mẹẹẹdogun (15,000) Naira.

CP Ọlaiya ni nigba ti Mojiṣọla de si otẹẹli lo fi atẹjisẹ ransẹ si ọrẹ rẹ pe ibi ti Happiness mu oun lọ ko tẹ oun lọrun, nitori pe ko si ayẹyẹ Kankan to n waye nibẹ, ṣugbọn oun ati Happiness nikan lawọn wa ninu yara ti Happiness si n fa igbo.

Ọrọ ti wọn sọ gbẹyin niyi ti aago rẹ ko fi lọ mọ titi ti wọn fi mu ẹsun lọ si ileeṣẹ Ọlọpaa.

O ni, “Iwadii fihan pe Adebayọ Joshua Happiness tan Awesu Mojiṣọla lọ s’Ilọrin ni, o si gba yara fun un ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ lai si erongba lati ṣe ariya kankan.

“Iwadii tun fidi ẹ mulẹ pe Adebayọ Joshua Happiness tun gba yara fun obinrin miiran nileetura kan naa lati fi ṣe bojuboju fun iṣẹ ọwọ rẹ.

“Ni afẹmọju ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹjọ, ọdun 2024 yii, Adebayọ Joshua Happiness ṣeku pa Awesu Mojiṣọla, o fi oku rẹ silẹ nileetura naa, o si sa lọ pẹlu iPhone ati ẹgbẹrun marundinlogun Naira to jẹ ti oloogbe naa.

“Lẹyin naa lo pada si ilu Ọffa, o si fi iPhone to ji pamọ si akata rẹ.”

CP Olaiya sọ pe lẹyin ti ọwọ tẹ Happiness tan ni awọn obi rẹ n gbiyanju lati bo aṣiri awọn ohun to le jẹ bii ẹri lori iṣẹlẹ naa.

O ni dipo ki awọn oṣiṣẹ otẹẹli yii fi ọrọ naa to ọlọpaa leti, niṣe ni wọn lọọ gbe oku oloogbe naa sọ sori akitan nigba ti wọn ri i.

O fi kun un pe awọn ti mu awọn obi Happiness atawọn oṣiṣẹ ileetura naa, nitori wọn fẹẹ bo aṣiri ẹri lori iṣẹlẹ ọhun.

Ọlaiya ni lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn yoo foju awọn afurasi ọhun bale-ẹjọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here