Ilẹ̀ mọ́ bá ọ̀rẹ́ mẹ́ta kan ,kẹ̀ẹ̀kẹ́ Marwa ni wọ́n fi ń ṣe wáń-ṣaànsì láàrin ìlú
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbàlagbà bọ̀, wọ́n ní ọjọ́ gbogbo ni tolè, ọjọ́ kan ni tolóhun, bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí fáwọn jàgùdà ọ̀rẹ́ mẹ́ta kan tó jẹ́ pé wọ́n ti jingíri nínú lílo kẹ̀ẹ̀kẹ́ẹ̀ Marwa fi ṣe wáń-ṣaànsì láàrin ìlú kan tí wọ́n ń pè ní Rantya, ní ìpínlẹ̀ Plateau. Àwọn afurasí ọ̀daràn ọ̀hún ni: Umar Abu, Peter Ezekiel àti Kelvin Monday, tí gbogbo wọn pátá ń gbé ládùúgbó Rantya, ní ìpínlẹ̀ Plateau yìí kan náà.
Oun ti a gbọ ni pe wọn ti wa lẹnu iṣẹ naa tipẹ tawọn ọlọpaa agbegbe naa si ti n dọdẹ awọn oniṣẹ ibi naa ko too di pe ọwọ tẹ wọn lasiko ti wọn ja araalu kan lole dukia rẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, D.S.P Alfred Alabo, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, sọ pe ṣe lawọn afurasi ọdaran naa maa n gbe kẹkẹ wọn kaakiri aarin ilu, ti wọn aa si maa wa awọn araalu to fẹẹ wọ kẹkẹ Marwa lọ sibi ti wọn n lọ.
Loju-ẹsẹ ti ero kan tabi meji ba ti wọle sinu kẹkẹ wọn ni wọn aa ti fi oogun pa wọn lara, lẹyin naa ni wọn aa ja wọn lole dukia wọn. Ati pe foonu igbalode olowo iyebiye lawọn maa n saaba ji lọwọ awọn araalu to ba ṣagbako wọn.
Alukoro ni araalu kan ti wọn ti bọ silẹ lẹyin ti wọn ja a lole laipẹ yii, lo waa fọrọ naa to awọn leti, tawọn si bẹrẹ si i ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ko too di pe ọwọ tẹ wọn laipẹ yii.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita nipa iṣelẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe, ‘’Ọwọ wa ti tẹ awọn afurasi ọdaran mẹta kan to jẹ pe kẹkẹ Marwa ni wọn maa n lo fi ṣe wan-ṣaansi laarin ilu, ṣe ni wọn maa n foogun ba awọn to ba fẹẹ wọ kẹkẹ wọn sọrọ ko too di pe awọn yẹn wọle.
‘’Bi wọn ba si ti wọnu kẹkẹ naa tan ni wọn aa ti ja wọn lole dukia wọn, ṣugbọn ọwọ awọn ọlọpaa agbegbe naa to n dọdẹ wọn pada tẹ wọn, wọn si ti jẹwọ ipa buruku ti wọn n ko laarin ilu naa fawọn ọlọpaa bayii.
Alukoro ni awọn maa too foju wọn bale-ẹjọ, ki wọn le fimu kata ofin fohun ti wọn ṣe.