Ìjọba ìpínlẹ̀ ogun gba ìwé àṣẹ ilé ọmọ aláìníìyá ogún
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ìjọba ìpínlẹ̀ ògùn ti gba ìwé àṣẹ iṣẹ́ ilé ọmọ aláìníyàá ogún ní ìpínlẹ̀ náà.
Èrèdí ìgbésẹ̀ ọ̀hún kò sẹ̀yìn bí ìjọba ṣe sọ pé àwọn ilé ọmọ aláìníyàá ọẹ́ẹ̀ ọ̀hún kò tẹ̀lé àwọn òfin tó yẹ láti dáàbò bo àwọn ọmọ tó wà ní ìkáwọ́ wọn.
Kọmiṣọna fun ọrọ awọn obinrin, Adijat Adeleye lo fi ọrọ naa lede nibi ipade awọn to ni ile ọmọ alainiya, eyii to waye ni ọọfisi ijọba, ni Oke-Mosan, niluu Abeokuta.
Kọmiṣọna naa fi aidunu rẹ lede lori bi awọn ile ọmọ alainiya kan ṣe n ṣe nipinlẹ naa, to si sọ pe ijọba ipinlẹ ọhun ko si ni tẹwọgba irufẹ iwa bẹẹ rara.
O ni ijọba ipinlẹ ogun ko ni faye gba ki wọn maa ta ọmọ, ki wọn maa ṣe agbatọ ọmọ lọna aitọ ati fifi iya jẹ ọmọ alainiya.
Kọmiṣọna naa fikun pe ile awọn ọmọ alainiya gbọdọ ni oju aanu, wọn si gbọdọ maa ṣetọju awọn ọmọ wẹwẹ daadaa pẹlu abo to peye fun wọn.
O fi kun pe afojusun ijọba to wa lode nipinlẹ Ogun ni lati ri pe abo to peye wa fun awọn ọmọ naa ki ẹnikẹni ma si le lo wọn lọna ti ko tọ.
Adijat ṣalaye siwaju si pe gbogbo awọn to ni ile ọmọ alainiya gbọdọ tẹle gbogbo ofin to rọ mọ iṣẹ wọn.
O ni “nnkan bii ogun ile ọmọ alainiya ni ọrọ naa kan bo tilẹ jẹ pe kii ṣe gbogbo wọn lo n ṣe awọn ohun to tapa si ofin bii aitẹle awọn ilana fifi ọmọ fun alagbatọ.
“Ṣugbọn a ti gbẹsẹ le iwe aṣẹ ile ọmọ alainiya ogun, a fẹ lo akoko wa lati ṣe iwadii daadaa ki a si mọ pe wọn n ṣe awọ ohun to tọ.
“A ti sọ fun awọn ti a gba iwe aṣẹ wọn ki wọn kọwe ẹbẹ fun iwe aṣẹ tuntun mii lẹyin oṣu kan, a si ti fun awọn ti a ko gba iwe aṣẹ wọn ni ilana tuntun ti wọn ko gbọdọ yẹba kuro ninu rẹ.”