Baálé fẹ̀sùn àgbèrè kan ìyàwó ẹ̀ ní kóòtù, ladájọ́ bá tún sọ ọ́ sẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta

Baálé fẹ̀sùn àgbèrè kan ìyàwó ẹ̀ ní kóòtù, ladájọ́ bá tún sọ ọ́ sẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́ta

Fẹ́mi Akínṣọlá

Èsúró pàdí dà, ó ń lájá, ajá ọdẹ pàápàá pẹ̀yìndà, ó lé olówó ẹ̀ wà sílè. Òwe yìí ló ṣe rẹ́gí pẹ̀lú baálé ilé kan, tí ilé-ẹjọ́ sọ sẹ́wọ̀n nítorí tí ìyàwó ẹ̀ ń hùwà àgbèrè, tó sì ká obìnrin náà pẹ̀lú àlè rẹ̀ mọ ibi tí wọ́n ti ń bá ara wọn láṣepọ̀ lórí ìbùsùn kan náà tí wọ́n jọ ń sun nínú yàrá ẹ̀ gan-an.

Ninu ofin orileede Naijiria nibi, ko ṣe e ṣe fun eeyan lati fi ẹsun ọdaran kan ẹnikẹni lai jẹ pe oluwarẹ ni ẹri to daju lọwọ lati fidi ẹsun naa mulẹ. Ṣugbọn ẹri to daju ju lọ lati fi idi ẹsun iwa agbere mulẹ lọkunrin naa, torukọ rẹ n jẹ Fan, gbe siwaju adajọ ile-ẹjọ giga kan lorileede Taiwan, ṣugbọn ti kinni ọhun pada bu u lọwọ.

Idi ni pe kaka ki wọn lo ẹri naa lati da a lare gẹgẹ bii olupẹjọ, ki wọn si fiya jẹ olujẹjọ ẹsun agbere naa, ẹni to pẹjọ gan-an ni wọn fiya jẹ, wọn lo ji fidio iyawo ẹ ya lai jẹ pe o ti sọ fun onitọhun ti tẹlẹ.

Gẹgẹ ba ṣe gbọ, o ti to bii ọdun meloo kan ti Fan pẹlu ololufẹ ẹ ti ṣegbeyawo, ti igbeyawo ọhun si seso ọmọ meji.

Ṣugbọn ko pẹ ti wọn ṣegbeyawo ọhun lọkọ fura pe iyawo oun n yan ale, ki si i ṣe pe obinrin naa n ṣe iṣekuṣe rẹ nibi to jinna rara, inu ile ti wọn jọ n gbe gan-an lo ti n ṣe gbogbo ohun to n ṣe.

Eyi lo mu ki Fan dọgbọn ri ẹrọ ayaworan ikọkọ meji sinu ile wọn, o fi ọkan si abẹ pianó ti wọn gbe si ẹgbẹ kan yara ti gbogbo ẹbi wọn jọ n lo ninu ile ọhun, o si fi ekeji si ẹgbẹ ẹrọ kọmputa kan to wa ninu yara ti awọn mejeeji nikan jọ n sun. Mejeeji si daa bii pakute ti ọdẹ na dẹ si oju opo ti ẹranko n gba kọja.

Ko pẹ pupọ ti pakute ọhun fi ré, nitori ko ju ọsẹ meji pere lọ lẹyin naa lẹrọ ayaworan ọhun tu aṣiri iyawo ile naa pẹlu ale rẹ, to si ya gbogbo bi awọn mejeeji ṣe wọ inu yara lọjọ naa, ti wọn si jọ gbo ara wọn mọ ori ibusun nibẹ fun igba pipẹ.

Eyi lo mu ki ọkọ iyawo pinnu lati kọ ololufẹ ẹ silẹ. Ṣugbọn igbesẹ ti ọkunrin naa gbe lati kọ iyawo ẹ silẹ labẹle ko seeso rere, nitori obinrin naa faake kọri, o ni dandan, afi ki awọn mejeji máa fẹ ara wọn lọ.

Ṣugbọn awọn agba bọ, wọn ni imi tíńtín leti àwo gbẹgiri, ba a ba moju kuro nibẹ, ọkan ko ni i kuro níbẹ. Fan mori le kootu, o ni ki ile-ẹjọ fopin sí igbeyawo awọn. Njẹ ki lo de, o ni iyawo oun n huwa agbere, wọn ni bawo awọn yoo ti ṣe gba a gbọ, nigba naa lo dakẹ, o ni oun ko ni alaye kankan lati ṣe mọ wayi, ninu fìdio ti oun mu wa si kootu yii ladajọ ati gbogbo ero to wa ni kootu yoo ti foju ara wọn ri i kedere.

Amọ ṣaa, ibi ti olujẹjọ foju si, ọna ko bábẹ̀ lọ. Lẹyin ti adajọ wo fidio tan, o ni ọkọ iyawo gan-an lo huwa ọdaran, nitori ko lẹtọọ lati ya fidio ihoho iyawo ẹ lai jẹ pe onitọhun yọnda fun un lati ṣe bẹẹ, n nile-ẹjọ ba sọ olupẹjọ naa sẹwọn oṣu mẹta.

Lọdun 2022 la gbọ pe igbejọ ọhun kọkọ bẹrẹ, ti olupẹjọ to di ọdaran lojiji si pe ẹjọ kotẹmilọrun.

Ṣugbọn lọsẹ ta a wa yii nile-ẹjọ kotẹmilọrun paapaa dajọ, wọn ni iya ti wọn fi jẹ ọkọ iyawo ni kootu akọkọ gan-an lo tọ si i, nitori ko daa bo ṣe ya fidio iwa agbere ti iyawo rẹ n hu. Nitori naa, dandan ni ko fi ẹwọn oṣu mẹta jura gẹgẹ bi ile-ẹjọ akọkọ ṣe sọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here